Home LÁGBO ÀRÍYÁ Wasiu Ayinde gboeregejige, o ra ibinu moto kan soso ni 66 million naira
LÁGBO ÀRÍYÁ - March 28, 2018

Wasiu Ayinde gboeregejige, o ra ibinu moto kan soso ni 66 million naira

Ini-Edo
… Ini Edo fi milionu kan gilaasi oju…

Nigba ti Wasiu Ayinde n ko orin CONSOLIDATION ni b odun meedogbon seyin, ase ko tii gboregejige tan lasiko naa. O jo pe o sese gboregejige bayii ni o. Koda, o sese wa kando gan-an ni.
Idi ni pe owo re sese n bureke sii ni.
Apeere eyi ni pe leyin ojo die to se igbeyawo pelu ololufe re lojo to ti pe, Fathia Wasiu Ayinde, o ti ra ibinu moto kan ti won n pe ni Bentley.
Owo moto naa ko si po rara: ogota milionu naira o le mefa pere ni. Pere!
Wasiu sese yoju moto yii sita ni, nipa bo se gbe foto re jade lori ero alatagba.
Eyi tumo si pe gbogbo aye ni awon alariya Naijiria n je bayii.
Bi won se n fi ile nla nla yangan, naa ni won n fi moto ta kan-n-gbon.
Lara awon ti won ti se bee lenu ojo meta yii ni D’Banj, Olamide, Wizkid, Funke Akindele ati bee bee lo.
Sugbon sa o, Yoruba bo, won ni ohun to n wuni nii po lola eni, ologun eru ku, aso re ko ju meji!
Eyi lo difa fun gbajugbaja osere fiimu oyinbo ti a mo si Ini Edo, ti o sese ra awo oju (sunshade/glasses) eyo kan soso ni owo to din die ni milionu kan naira (N900,000).

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja

Iléeṣé ológùn ti sìnkú àwọn akọni tó bá ìjàmbá ọkọ̀ Bàálù lọ ní Abuja Ọrẹ Òtítọ́jù Àwáyé è…