Home iroyin Olopaa fesun odaran kan Melaye ati awon kan
iroyin - March 20, 2018

Olopaa fesun odaran kan Melaye ati awon kan

Dino Melaye ni Seneto to n soju ipinle Kogi ti awon kan ni ipinle naa ti n gbero ati pee pada nitori pe won ni ko soju awon daadaa. O gbe ajo INEC lo si ile-ejo, ile-ejo si ni ki awon ajo INEC te siwaju lori igbese won.
Oun naa ni awon omo ipanle ti owo awon olopaa te ni ipinle naa tun daruko pe oun lo ran awon nise. Fun anfaani awa ti a ba ti n tele iroyin orileede yii lati bii ose meji seyin, a maa gbo pe apa kan ni ipinle Kogi ko ni isinmi, ija lonii, ija lola ni o n sele to o si n mu emi awon eniyan lo.
Agbenuso awon olopaa ni ipinle Kogi lo n ba awon oniroyin soro pe, lara awon ti owo awon te to n je Kabiru Saidu ti ko ju omo odun mokanlelogbon (31) lo, ti alaje re n je Osama, elomiran ni Nuhu Salisu omo odun meedogbon (25) ati Muhammed Audu.
Agbenuso olopaa ni awon odaran yii jewo pe Dino Melaye ni awon n sise fun, oun lo ra ibon AK – 47 repete fun awon, Osama ni owo ti oun gba lowo Melaye lati fun awon toogi to ku je egberun lona irinwole logbon naira (430,000.00). Awon olopaa ni awon n reti Dino Melaye ni Lokoja lati wa koko salaye ara re lati ojo keje osu keta odun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…