Home Orisirisi Lilo si soosi ati mosalasi ko le so e di olowo bii Dangote – Femi Otedola
Orisirisi - March 11, 2018

Lilo si soosi ati mosalasi ko le so e di olowo bii Dangote – Femi Otedola

Okan pataki ninu awon olowo Naijiria, Alagba Femi Otedola, soro nipa ipa ti ayanmo ko ninu bi o se di olowo …

Wobi, ohun ti o daa ni ki eniyan se eto, ni ipinnu ati ifojusun lori oro ayee re, ko awon ifojusun re sile, ipo ti o wun o ki o ti de nigba ti o ba maa fi pe omo ogoji odun amo je n so fun o omo iyaa mi lokunrin lobinrin, owo Oba oke ati kadara ni opin gbogbo re wa.
O seese ki o je wi pe iwo naa ni eni ti o fi owo ya bi kadara re yoo se ri amo sibee naa… ko si biotile wu ki o tiraka to, oo le moribo nibi ohun ti Oba oke ti koole fun o…
Ti eyi bati ye o daadaa, oo rii wi pe lilo si soosi ni gbogbo Sunday, sisan ida mewaa daadaa, sisin alufa, wolii abi pasito re abi ki o maa kirun leemarun lojumo gege bii Musulumi ododo ko le so e di olowo bii Dangote ti ayanmo ati kadara re ko ba gba fun o lori eleyii.
Gbogbo iberu Olorun ati isesin daadaa ninu awon esin, ko si tabi sugbon yoo gbe e wo paradise; amo o le maa yii ipo ti o wa lowolowo yii pada laye abi ki o ko wa di ilumooka leekan naa.
E bi Wizkid abi Davido bi won kan se dede di gbajumo akorin lonii, esi ni pe won ko lee salaye, won kan ni ifojusun bii awon olorin miiran ti won jijo je egbe ni, amo iyato ti n be laarin awon olorin kekeke wonyi ti wo n tiraka lowo lati dide si awon mejeeji yii ni pe ilakaka awon mejeeji kan koore ni, ti awon akorin ti o ku pelu ohun ti ori won yan ko kan lee so won di gbajumo bi awon naa se di gbajumo lonii.
Ko tunmo wi pe Wizkid ati Davido gbon ju won lo abi won ja fafa ju won lo, oro bi aye se n sise tire lasan ni.
Je ki n ja e si eleyii lofee, o ni ipo ti imo iwe ti o ni ati ijafafa re le gbe e de laye, bi o ba fe gbo oro yii ye daadaa, wo eni ti o gbari julo nigba ti o si n be ni ile iwe giga, wo ibi ti won wa lonii ati ohun ti won ti ri gbese laye won di akoko yii, se afiwe won pelu awon ti won ko gbari to won nigba naa loun. Wa rii wi pe onikaluku ti tesiwaju lori irin ajo re ti okan ko jo ikeji ti ko si niun se pelu tani o mo iwe ju nigba naa tani ko mo.
Ile aye yii ko ni ofin kan abi ilana kan ti eniyan le fi laluyo, eni ti o ba n so idakeji eyi fun o n tan e ni, iro lasan ni n pe fun e.
Ecclesiastes 9:11 salaye eleyii daadaa nigba ti n so bayii pe:
“Mo pada, mo si ri nnkan miiran labe oorun, pe ire ije ki i se ti eni ti o yara, bee ni ogun ki i se ti alagbara, bee ni ounje ki i se ti ologbon abi oloro, bee ni oro ki i se ti eni oloye, bee ni ojurere ki i se ti ologbon-inu; sugbon igba ati aye n waye lori gbogbo won pata.”
Ti gbogbo awon nnkan wonyi ba ye o daadaa, idaamu re laye lori bi aye re se ri yoo dinku, ti oo maa gba ohun ti ojo kookan ba mu wa.
Ma si mi gbo o, o dara ki eniyan ni akolekan ki o si maa tiraka lori ohun ti n wa, ki o ni ifokansun ki o si jara mose amo nigbeyingbeyin, bi o se rise si ko niun se pelu bi o se gbari si abi bi o se sin olorun si bi kii se wi pe ayanmo,igbalaaye ati adura iyaa re lo gbawaju.

LASU ti setan lati maa ko gbogbo akeko ni eko Yoruba – Dokita Adesanya Ahmed
….Omowe Adesanya Ahmed, to je Oluko Agba ni Eka Eko Imo Ede Yoruba, Litireso ati Ona ibanisoro, ni Yunifasiti Ipinle Eko, Lagos State University, ba oniroyin wa, Afeez Adekunbi, soro lori bi ijoba Ipinle Eko se pon ede Yoruba ni dandan ni kiko ni awon ile iwe

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò

Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…