Home Orisirisi GODDY ANABOR: Eko pataki ninu oro olowo tabua tele to di edun arinle
Orisirisi - March 11, 2018

GODDY ANABOR: Eko pataki ninu oro olowo tabua tele to di edun arinle

Ninu iforowanilenuwo kan ti won ti gbe s’ori ero alatagba, okunrin gbajumo olowo kan tele, Ogbeni Goddy Anabor, soro lori bi obiri aye se de ba a
“Ni ile itura Sheraton l’Ekoo, mo na milionu merindinlaadorun naira (N86m) lati gbalejo awon eniyan lati London fun odun kan ati osu meta. Iwe akosile owo yii n be lowo mi, e si le lo bi won nibe. Lonii nnkan ti daru fun emi ati awon ebi mi; koda mi o mo ohun ti mo le so mo.
“Mo n ri orukoo mi ninu gbogbo iwe iroyin mi o si mo idi. Emi ni mo ko awon eniyan bii Chris Sogunro, Tokunbo Sodunke, Dare Babayemi, Wale Awesu, ati bee bee lo nise. Emi ni mo so won di nnkan ti won da lonii, lonii olowo repete ni won. O ya mi lenu wi pe won ri mi ninu ipo ti mo wayii; awon miiran ninu won so pe mo n gbe egboogi oloro, amo won ko le ran mi lowo. Mo ko mo idi ti won fi je alaimoore bi eleyii.
“Arakunrin kan ti won n pe ni Mike Biggy ti n gbe ni agbegbe Akowonjo nikan ni o ti ran mi lowo. O gba ile fun mi o si n toju mi daadaa. Idi ti awon eniyan wonyi se pinnu lati huwa aimoore si mi bayii ko ye mi pelu gbogbo iye owo ti mo na lori won.
“O ni igba kan ti mo ni bilionu meta ni ile ifowopamo Equity ni agbegbe Allen Avenue, Ikeja, ti mo na fun awon eniyan. Koje bi o ti je naa, mo si dupe fun Olorun lori aye mi.”
Iwonyi ni oro gbajumo olowo Pataki kan tele, Alagba Gody Anabo, gege bi o se so fun awon oniroyin ninu iforowero Pataki kan. Okunrin naa je olowo tabua ati alafe aye pupo tele, to maa n nawo ni eleda fun awon osere. Idi niyi ti awon alare bii Kollington Ayinla ati Wasiu Ayinde fi maa n k i i ni aki-fee-pa. Sugbon baii o, igba ti yi biribiri.
Goddy Anabor tubo so siwaju, “Emi ni mo bere tite iwe jade ni orisiirsii awo ni Naijiria, mo n te iwe iroyin jade fun ile ise iwe iroyin Thisday(Thisday Newspaper),Punch ati iru won bee bee lo. Mo tun se akosile ile ise eto abo kan ti won si fonte lu u mo si ni iwe eri. Awa meta ni won fun ni iwe eri yii (License). A ni Vanni, Gordon ati ikan ti o ku. Emi ni mo tun daabo bo ibudo oko ofurufu.
“Eni nla ni o nigba naa; se oko fi ogbon ko owo re sori awon nnkan nigba n ni ni?
Opolopo ninu owoo mi ni mo ko le orisiirisii nnkan, amo nitori iwa ibaje,ise nnkan kumokumo awon eniyan ti won n moju to awon owo wonyi, ni gbogbo re ba denu koile. Bi o ba ni owo ti o n se, o dara pupo ki o gba awon ti o se gbarale sidi re ki o si fun won ni ohun ti yoo dun mo won ninu, ninu owo ki o le baa jere okan won. Eko kan ti o kaya ti mo ko niyii. Iyawo ati awon ebi mi ni mo fi si idi re ni won ba da oju aje bole. Iyawo mi ti n je Anthonia tun n pin owo pelu awon eniyan nibikara-kata. Awon osise mi n kole ninu owo ti won n ri nibi owo wonyi ti mi o si mo si i.
“Ago olopaa ni mo ti pade e nigba kan ti mo ni isoro kan. Olopaa ni nigba yen, ti o rewa pupo. O n sise pelu Dan Baba nigba naa loun bee o si n gbiyanju lati ran mi lowo. Iyawo mi akoko je omo ijebu ti n je Toyin, o si n be laye bayii. Mo maa n pe e ni Toyin Tomato; gbogbo igba ni o maa n fi wa pelu Kolington, Tayelolu ati awon bee bee lo.
Mo ko obinrin naa nitori o nife si ayeye lilo pupo. Emi naa maa n lo awon ayeye, sugbon mi o le fi awon ebi mi sile ki n wa gba ayeye lo. O maa n fi omo wa okunrin kekere sile lo si ayeye lorisiirisii. Omo meta ni o bi fun mi. Omobinrin mi akoko, Bose ti gboye Phd ni London. Mo tun ni imii ninu won ti o je Dokita, ati Tunde ti n be ni America.”
O tun soro lori awon dukia re kan to wa ni Isaac John ati Alabi Crescent ni Ikeja:
“Won re mi je nitori won mo wi pemo nilo owo. Won fi ogorin milionu lo mi lati owo arakunrin kan ti won n pe ni Basorun A.K. fun dukia ti n lo bii oodunrun milionu. Atimole ni o wa bayii lati nnkan bii odun mewaa seyin nitori o n ta egboogi oloro.
Ile igbalejo re n ko? ni Joel Ogunnaike,GRA, Ikeja.
Mo ya a lo ni, mo si ti gbe e le fun Shina Eddo, ti oun naa ya a lo lowo awon ebi ti o ni i. Eniyan daadaa ni Shina si mi.

Awon oko re bogini bogini re n ko nitori mo mo wi pe nifee won gan-an?
Mo ni oko ti n lo bii aadota bii Bentley, Rolls Royce ati awon miiran bee. Awon oko ti won sese se jade ni mo maa n sabaa ra. Otaale ni isoro ti mo ko nile aye mi. Olorun ti je ki n rii wi pe awon eniyan ti mo fokan tan ko tie laaanu mi loju rara.
Kini o de ti o fi ro wi pe awon eniyan pa e ti?
Iwa ibaje ni, aisefokantan. Ohun ini mi ti n lo bii ida ogota ni mo fi fun opolopo eniyan. Inu mi maa n dun ladugbo nitori awon eniyan bii Ade Balogun maa n toju mi.
Bawo wa ni Dare Babs se je si e?
Oun ni eni ti n wa mi kiri nigba naa. Mo mu u wa lati Abeokuta wa si Eko nigba ti mo si n sise ni ile ise oti. Isoro kan lo waye lori owo kekere kan bii milionu marun-un dolaasi, ti arakunrin kan ti won n pe ni Kenny ji, biotilejepe a ti yanju re. Eniyan gidi ni, amo o ti pe pupo ti mo ti gbo lati odo re.

Ibasepo wo lo wa laaarin iwo ati Oghadiome?
Egbon-on mi labule ni o je; koda egbon mi lagbole ni ni Fuga ni Ipinle Edo. Oloogbe Admiral Akhigbe ni gomina ipinle Eko nigba naa; O jo bi eni wi pe ohun ni o fi Oghadiome je igbakeji gomina fun Lucky Igbinedion ti ipinle Edo. Nigba ti o di oloye awon osise(chief of staff) fun Jonathan, Mo lo Abuja lati lo ri i. Mo n lero wi pe yoo pe mi fun nnkan gidi nitori nigba ti iya re ku, mo n be nibe. Koda nigba ti won n ko ile ise ijoba (Secretariat) ni fujar, emi ni mo dawo ju ti won si so gbogan kan nibe lorukoo mi:Godwin Anabor Hall. Lonii, ko si eni ti o da mi mo ninu won, eyi si pani lerin pupo.
N je o lero wi pe ohun ti n se e yii afowofa ni nitori o maa n ‘gba’ owo lowo awon eniyan nigba yen?
Ninu Bibeli, Olorun so pe, “Bi o ba gba Olorun gbo, yoo fun e ni ayo. Amo fun awon ti won ko gba a gbo, yoo fun won ni agbara lati kowo jo, amo awon ti won ni igbagbo ninu re yoo gba a lowo won.” Olorun lo fun mi lowo; mi o ja a gba lowo enikeni, o wa ni. Ti o ba je wi pe mo gba a lowo awon eniyan ni won a ti ti mi mole. Won ko fi esun kankan kan mi ri bee mi o si sun ewon ri fun idi kan tabi ekeji. Akosile bee ko si fun mi.
Ti oo bamo, mo mo wi pemo si maa pada sori esee mi mejeeji; nitori naa ni mo fi n soro bayii. Nitori dandan ni ki o lo soke ki o si wale fun bi eemeje ki o si tun ri oore ofe gba. Mo gbagbo bee ninu Olorun.
Kini ohun ti o dun mo e ninu julo laye?
Idunuu mi ni wi pe mi o ku ti mo si fun awon eniyan laaye lati fohun rere nipaa mi nigba ti moba lo tan. Mo n be laaye lati ri bi awon eniyan se n se si mi nigba ti mi o ni mo. Koda awon eniyan ti mo ko bi won se n peja nigba naa loun ti won si ti di olowo bayii ko fe fi owo kan mi.

So nipa ibere ayee re fun mi, nibo ni o ti wa?
Fugar ni mo ti wa, Auchi ni ipinle Edo, amo ilu Kano ni won bi mi si, mo si dagba ni ilu Osogbo.
Ade Bendel n ko, mo gbo wi pe oree re ni?
Bi omo iya ni o je si mi nitori Owan ni o ti wa ni ipinle Edo; Eko ni a ti pade. Mo gbo wi pe o ko awon wahala kan pe o wa ni ewon; ohun ti momo nipa re lowo lowo niyen.
Ti o ba pada di olowo, eko wo ni o ti ko laye?
Mo fe ki awon eniyan mo wi peawon ore ti o ni lowo lowo kii se ore re ayo re; koda awon ebi re gangan ni ota ile re. Iwo ati olorun nikan ni, gba a bi mo se so fun e un. Maa weyin wo loorekoore.
Kini o ku fun e bayii?
Olorun ni o ku mi ku, o n dara ninu aye mi nitori mo si n be laaye mo si n gbadun aye mi. Mo si nigbagbo ninu oro bibeli Filipiani 4:13. ‘gbogbo nnkan ni mo le se latara eni ti o fun mi nipa.’
Won ni o ti n wa oko akero bayii, se ooto ni?
Nnkan ti o wu awon eniyan ni won n ko. Opolopo eniyan ni o fe fun mi ni awon oko ati awon nnkan miiran. Bi Olorun ba ti ke o, o ti ke o naa nu un. Se oo ri awako ti n gbe mi kiri ni, bee ni, o maa n gbe mi kiri pelu oko ti won n pe ni Toyota Pencil light, amo kii se emi ni mo n wa oko abi se kabukabu pelu re. Mo ti kekoo lati gbe pelu ipo ti mowa yii sibe mo si n be laye lati ri gbogbo eleyii.
Kini adura ti o po lenu re ju si Olorun?
E maa ri adura mi ninu iwe Psalm 1 ti o so pe, ‘oriire ni ti eni ti ko rin laarin awon osika.’ O ni oun yoo ke won yoo si so won di bii awon igi ti won gbin si etido. Ohun ti mo gba ladura niyi,i pe ki n lowo lowo. Gbagbe ofofo ti awon eniyan n se.

Kini ojo ori yin bayii oloye?
Omo odun marundinlogota ni mi, ojo kokandinlogun osu keji ni won bi mi.
Nibo ni Anthonia ati awon omo re wa bayii?
Won n be ni London.
Kini oro igbeyin re?
Ohun ti maa fi gbeyin gbogbo oro mi ni pe ki gbogbo eniyan maa sora se ki won maa weyin wo, nitori awon ota ile n be.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…