Home Orisirisi Iro nla ni pe emi ati Alaafin ko gbodo foju kan ara wa mo – Gani Adams
Orisirisi - March 5, 2018

Iro nla ni pe emi ati Alaafin ko gbodo foju kan ara wa mo – Gani Adams

Sosomeji Ebora Owu ati Aare Ona Kakanfo naa pade

Aare Ona Kakanfo ile Yoruba, Otunba Gani Adams, ti so pe iro pata ni pe Aare Ona Kakanfo ko gbodo foju kan Alaafin mo leyin ojo ti o ba ti gba opa ase.
O ni awon alaheso eniyan lo n so iru oro yii, to di fi kun pe oun ati Oba Lamidi Adeyemi yoo maa pade ara won ni gbogbo ibi to ba ye.
Aare soro yii ni ilu Eko lojo Jimoo, nigba ti awon egbe Gbaareniyi n se apejo kan fun un.
Gbongan LTV ni Agidingbi, Ikeja ni eto naa ti waye.
Nibe ni opo awon oba alaye ati asiwaju esin ti se adura fun Aare ti won si fi idunna han si igbese to n gbe lori idagbasoke ile Yoruba.
Ninu idanilekoo kan ti Ojogbon Michael Omolewa se, o so itan awon Aare Ona Kakanfo to ti wa, ipa ti won ko ati ohun to sele lasiko ti won.
Ojogbon Omolewa ni o dara bi gbogbo eniyan se n gbaruku ti Aare Gani Adams tori o ni awon eto gidi fun omo Kootu Oojiire.
Bakan naa, Aare Gani Adams ati Aare orile-ede yii tele, Oloye Olusegun Obasanjo, foju rinju lose to lo, nigba ti won pade nibi ayeye ojo ibi aadorin odun Dokita Dosunmu Awolowo, ni ilu Ikenne.
Bii wi pe ore aja pelu ekun lo wa laarin Obasanjo ati Gani Adams tele.
Leyin pe won jo gbo ewuro sira won loju nigba ti Obasanjo wa ni ijoba, ti awon OPC gbona bi elegun Sango nigba naa, oro oye Aare Ona Kakanfo naa tun fe gbe awon mejeeji kolu ara won.
A gbo pe Obasanjo naa nifee si oye nla naa.
Bakan naa awon kan so pe ko nife si bi Alaafin se fi Gani Adams se Aare. Won ni idi niyi ti ko fi lo si Oyo lojo ti won gbe opa ase fun un.
Sugbon ni ilu Ikenne, awon mejeeji rira won, ti won sit un jo bowo. Ohun to wa lokan onikaluku la ko mo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19.

Ààrẹ Buhari àti igbákejì rẹ̀, Yemi Osinbajo ti gba abrẹ́rẹ́ àjẹsáèra Kófíìdì-19. Ọrẹ Òtítọ…