Home Orisirisi Bi ere bi awada, awon agbaagba inu fiimu Saworo Ide ti fee ku tan
Orisirisi - March 5, 2018

Bi ere bi awada, awon agbaagba inu fiimu Saworo Ide ti fee ku tan

AKINAKINETakinwumi isolaTK
… Yegede, Tunde Kelani di eni aadorin odun

Ominu ti n ko awon ololufe fiimu Yoruba bayii, latari bi awon agba osere inu fiimu Saworo Ide ti n lo je Olorun nipe.
Fiimu naa je okan ti o gbayi gidi, to si wa lara ogo Yoruba. Alagba Tunde Kelani lo gbe e jade.
Dokita Larinde Akinleye lo koko je Olorun nipe laarin awon to se e.
Inu ijamba moto ni o ti gbemii mi.
Aipe re naa ni Ayangalu ku – eni to n fi ilu powe Saworo Ide ninu fiimu naa.
Alagba Laide Adewale naa ti lo sibi agbaa re, ti oun naa lo ni nnkan bi odun mefa seyin, leyin ti o ni wahala kan ninu ikun re.
Laarin bii osu mefa seyin, awon agba osere inu Saworo ide naa tun ti lo.
Awon ni Alagba Adebayo Faleti ati Ojogbon Akinwumi Isola.
Sugbon iku agba, iku ogbo ni awon mejeeji ku.
Ni bayii, ohun kan to n dun awon ololufe Tunde Kelani ninu ni pe oun naa ti di eni aadorin odun.
Opo ayeye ni awon ololufe re si n seto fun un.
Kelani je gbajugbaja onifiimu ti feran asa Yoruba dunju.
O maa n lo fiimu lati gbe ogo ile Adulawo yo.
Lara awon fiimu to ti se ni Ayo ni mo Fe, Ti Oluwa ni Ile, Saworo Ide, Magun, Koseegbe, Maami ati White Handkershief.
Oro ti Davido so nipa orun da ipaya sile laarin awon ololufe re
Akorin hip hop ti a mo si Davido da ipaya sile laarin awon eniyan re, nigba to so pe orun (heaven) n wu oun.
O ni oun setan lati foju kan Paradise.
Eyi wa di ohun ti awon eniyan n tumo si orisiirisii ona.
Nigba ti awon kan so pe o fi n sere ni, awon kan n bee pe ki o ni suuru, ki o ma se biii ti Dagrin to je pe o papoda lojo aipe.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…