Home iroyin Asewo ati Oloogun niyawo mi
iroyin - March 5, 2018

Asewo ati Oloogun niyawo mi

Ogbeni Gafau Shogaolu ti ko tii ju omo odun meedogun lo to si tun je Mekaniiki to n gbe ile ketala, opopona Sijuade ni Abesan, Ipaja to wa ni Eko lo ke gbajare ni ile ejo to fi ikale si iyana Ipaja, pe ki adajo jowo je ki iyawo oun maa lo ki emi oun le gun.
O ni oloogun paraku ni iyawo oun nitori pe omo re kan ka oogun moo lowo ri nigba ti oun naa ti ri agadagodo kan ti won ti pa pelu owu pupa ni inu eru re.
O ni eti oun gan an tun ti kun ni adugbo nitori iwa agbere ti iyawo oun n wu kiri igboro, o ni bi dudu se n gbee jade ni pupa n gbee. Gafau ni oun funra oun gan-an ti rii to n wo inu moto ayokele onisegun kan ti oun mo.
Oko yii ni ara awon iwa pala-pala re naa niyi ti o fi ja lo lati nnkan bii odun meedogun seyin ki oun to gbaa pada nigba ti ebe po. O ni ki o to de ni oun ti fe obinrin miran ti o si mo. O ni eyi ni ko je ki oun je ki awon mejeeji gbe po, oun ni lati lo gba ile fun un ni ibomiran ni.
Maria to je iyawo Gafau ti ko ju omo odun merinlelogoji salaye fun ile-ejo pe oun ko kii n se oloogun rara, oogun ti oko oun n salaye je eyi ti Micheal aburo oun mu wa n ojo kan. Nipa ti agbere, o ni iro pata-pata naa ni gbogbo re, o ni loooto ni baba onisegun naa fi oro ife lo oun ti oun ko si gba fun un. O si salaye fun ile-ejo pe ibi ti oun ti se asise ni pe oun ko so fun oko oun. O si ro ile-ejo ki won ma se tu igbeyawo naa ka nitori pe oun nife awon omo oun ati oko oun.
Onidajo Adekunle Hassan se ikilo gidi fun Maria pe ki o lo so ewe agbeje mo owo, o si tun ni nnkan buruku kankan ko gbodo sele si idile oko re. Eyi mu ki o sun igbejo naa si ojo kejilelogun osu karun-un odun yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…