Home iroyin A ko fe lo ileewe mo – Akekoo Dapchi
iroyin - March 5, 2018

A ko fe lo ileewe mo – Akekoo Dapchi

Awon akekoo to sa mo awon Boko Haram to wa ji won ko ni ojo Aje to koja ti se ileri pe awon ko fe pada si ile-iwe naa mo. Won ni awon Boko Haram naa wa si ile-iwe awon pelu aso ologun. Won si salaye fun awon pe awon ko mo pe awon omo naa wa ni ilu naa, awon ko ba ti wa lati ojo to ti pe, sugbon bayii ti awon ti mo, awon tun n pada bo.
Gbogbo ipede yii ni awon akekoo naa ni awon gbo ti o si n seru ba awon. Won ni opelope iranlowo awon oluko ati ara awon ni awon fi sa asala mo awon eniyan buruku naa lowo.
Awon kan ninu awon marun-un to ba awon oniroyin soro ni awon tile le pada ti ijoba apapo ba pese aabo to daju fun ile-iwe naa. Awon akekoo naa ni – Mariam Mohammed Miko, Amina Abubakar Mohammed, Fatima Mohammed ti won jo je omo odun meeedogun, Yagana Mustapha ati Ajara Lawal ti won je omo odun merinla.
Ninu awon akekoo yii ni a ti ri awon to sese kirun tan ni mosalasi ile-iwe naa ti won si ni awon gbo iro ota ibon to dun bii bonbu. Won ni eru ba awon, enikan ninu awon ni, Boko Haram lo n ba awon ara abule awon ja. Won ni omiran ti awon maa gbo sun mo awon gan-an ni eyi to mu ki oga ile-iwe naa ni ki onikaluku sa asala fun emi re.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…