Home Orisirisi Lere Paimo sedaro Akinwumi Isola
Orisirisi - February 21, 2018

Lere Paimo sedaro Akinwumi Isola

Nnkan nla se nile Yoruba, igi da
Kinniun oloola iju lo lo nigbo
Akoni lare, akoni lorin, akowe, akewi nla
Akinwumi Isola peyinda
O di gbere, akomolede tii p’ede ara…

Agba osere, Alagba Lere Paimo, ti ki ogbontarigi onkowe, Ojogbon Akinwumi Isola, pe o digboose.
Nigba ti Lere Paimo, ti a mo si Eda Onile Ola, n soro lori iku Akinwumi Isola, o ni eni kan to feran asa ati ede Yoruba de gongo ni.
O ni o tun je eni to niwa irele, to si nifee omolakeji.
Paimo ranti igba ti Akinwumi Isola sise pelu oun ati awon osere yoku lori fiimu Saworo Ide.
O ni o se gudugudu meje ati yaaya mefa.
Gudugbe ja ni ile Yoruba, nipa iku oluko, akewi ati osere agba, Ojogbon Akunwumi Isola, lojo Satide.
Ilu Ibadan ni isele nla nag be se, to si n mi gbogbo ilu titi.
Loooto, iku Ojogbon Akinwumi Isola kii se iku ofo, oku eko ati oku amala ni.
Sugbon iku naa n ja awon amoye aya nitori pe okan ninu awon to di opo asa ati ise Yoruba mu ni.
O tun seni laanu pe isele naa se ni ai tii pe odun kan ti ogbontarigi asa miiran, iyen Alagba Adebayo Faleti, peyin da.
Ore timotimo ni awon mejeeji je, to si je pe bii moyami ni won. Boya kadara won naa lo ba won to o bee, pe ki won tun maa ba ore won lo lorun.
Gbogbo eniyan, to fi mo awon goina lo tin n daro Isola.
Bee naa ni awon onimo ijinle bii Ojogbon Femi Osofisan ati Ojogbon Tunde Babawale.
Won ni igi nla gbaa lo da, to si je pe a ko le ri iru eniyan bee mo.
Leyin wi pe Akinwumi Isola ko opolopo omo ileiwe jade, ti awon naa si ti n di dokita ti won ti n di adajo, o tun je eni kan to mu idagbasoke ba litireso ati ere onise, to fi mo fiimu Yoruba.
Alagba naa ni o ko awon iwe aladun bii O le Ku, Efunsetan Aniwura, Ko See Gbe ati Saworo Ide.
O si kopa ninu opo fiimu.
Nje ki Olorun te baba na si affe rere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…