Home iroyin Aare Ona Kakanfo se ikilo pataki lori jagidijagan Fulani darandaran
iroyin - February 21, 2018

Aare Ona Kakanfo se ikilo pataki lori jagidijagan Fulani darandaran

Otunba Gani Adams ti o je Aare Ona Kakanfo ti ile Yoruba ti so o di mimo pe awon eniyan ti won n be ni Iwo Oorun-Guusu ile wa ko ni se igbalaaye fun Fulani deranderan lati so ilu won di papa ipaniyan.
O so eleyii di mimo nigba ti o tenu mo oro bi emi se n bo lori oro awon fulani deranderan yii kaakiri ile Naijiria.
Adams tun pe aare Muhammadu Buhari pe ki o tete pa a lase fun awon ajo eleto abo lati “ gbe awon mujemuje ti won po yii ninu ilu, ti won n fi awon deranderan boju, ki owo ofin te won ki won si lo ofin le won lori ki o to di wi pe apa ofin funra re naa ko ni niyi mo.”
Aare so eleyii di mimo ninu oro re kan ti o gba enu oluranlowo re so lori Midia, Kehinde Aderemi.
O tun ni orokoro ni pipa ti won so wi pe awon Fulani deranderan pa osise olopaa ti n dari awon Special Anti-Robbery Squad (SARS), ti Saki, ti ajo olopaa ipinle Oyo.
Oro naa lo bayii: “ Eyi ti o je akoko ninu eto omoniyan ni eto bibe laaye re. Nigba ti o ba wa laaye ni wa a le gbadun awon eto ti o ku. Niwon igba ti won ba ti gba eto akoko yii lowo re nipa pipa ati ogun ipaniyan, oo le gbadun eto kokan mo. Awon omo Naijiria n beere fun eto si wiwa laye ati laaye. O ti ju egberun kan omo Naijiria ti won si pa ni odun kan soso ti o koja. Se ilu Naijiria n be ninu ogun ni? Nnkan miiran n be labe gbogbo eleyii”
“ E maa fi isejeje ati idasi awon omo yoruba lori awon ohun ti n lo ni orile-ede wa, paapaa julo awon eyi ti n da eto aabo laamu ni pe ojo o. Ninu iseda ti wa ni ki a maa sepo pelu awon eniyan eya miiran, ki a gba won lalejo si aarin wa, amo bayii awon eniyan wa ko lee loko mo nitori ifoya ti won ko le juwe re yii. Ijoba apapo ni lati foju sile ki won se ayewo finni-finni lori awon eto ati igbese awon eniyan laabi yii ki o di wi pe ogun tipatipa yoo wa beele ninu ilu yii.”
“Ko si ogun ninu ilu yii, iyan ko da wa laamu, ko si iji ile, amo onka awon IDPs ti n be ni ilu Naijiria ju ti eyi ti a maa ri ninu ile ti ogun n ja lowo. Pipa awon eniyan, ti ko fi oloyun, awon omo kekeeke sile n waye lojoojumo. Kini nnkan ti n sele gan-an?
“Gbogbo nnkan ni n fe ironu jinle si. Ijoba apapo ko so ara re lorukoo ire pelu igbagbo opolopo awon omo Naijiria lori pe Aare Buhari maa n dake ni ti o ba di oro awon Fulani deran-deran yii.
“E je ki n ran awon ijoba wa leti pe ki won maa gbagbe wi pe ipaniyan ati ifemisofo, ese nla ni ninu iwe ofin wa. Ko si ipo kan ninu eto oselu ti o le yi eleyii pada. Won n pa awon omo Naijiria o si da bi eni wi pe awon ijoba ko lee se ohunkohun si I. Awon oro ti n jade lenu minisita eto abo, Brig- Gen. Mansur Dan-Ali (retd), ati ti oga olopaa, Inspector Gen. Ibrahim Idris ko se atunse ohun ti n be nile yii. A maa seni leemo wi pe se inu ilu kan naa ni awa ati eniyan wonyi jo wa bi.

“Ni ibi ti ko si ifokanbale ati abo, ko si tabi sugbon deedee ko lee ri idi jokoo nibe. Ki a le se amulo ofin, awon ti won je osise abo ni lati se deedee laarin gbogbo ara ilu. Ipaya gba okan gbogbo omo Naijiria nigba ti won ji sinu odun titun ti o wa je wi pe iroyin ipaniyan ni ipinle Benue ni won koko ji gbo. Ni bayii awon omo Naijiria ti won n gbe ni Nasarawa, Taraba, Adamawa, Kogi ati bee bee lo won ko ni ifokanbale lori emi ati dukia won mo. Ipani lainidii kan pato da bii aarun jejere ni ti a ko ba tete moju to o, o le fa ikoti ikun si ofin patapata nitori awon omo Naijiria naa ni eto lati daabo bo ara won lonakona.
“Ninu itan, won mo awon eya Yoruba gege bi eya ti o ni ikapa ati daabo bo ara re. Awon apaniyan wonyi n to omi wo pelu bi won se sun oko oloye Olu Falae ati bi won se n ja lu oko awon eniyan nla nla ni iwo oorun guusu ile wa. A ko ni fi aye gba ise ibi owo awon wonwonyii mo laarin awon omo Yoruba ati ile won. O to gee bayii.”

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́, Shoprite, bẹ̀rẹ̀ ìfẹ̀hónúhàn káàkiri àwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà. Orẹ Òtítọ́…