Home ÀRÒJINLẸ̀ Eranko meta to n daamu Naijiria
ÀRÒJINLẸ̀ - February 19, 2018

Eranko meta to n daamu Naijiria

Ilu nla to ni okiki kaakiri agbaye ni Naijiria. Eyi si tun tete ran mi leti orin oloogbe Sikiru Ayinde Barrister to koo bayii … “okiki ti mo ni yii ko i to o, Oba oke ba mi wa mii sii o Edumare…” ati bee bee lo. Ojumo kan, ara kan.
Eranko meta wa ti itan won ko le tete pare kiakia lorileede yi. Merin lo ye ko je, sugbon ti ekerin ko fese mule daadaa. Eranko kerin naa ni obo ni asiko arun Ebola. Eyi ko ran ile bi ti awon to ku yii.
Eranko akoko ni EKU, eku ni o le odidi Aare Mohammadu Buhari kuro ni ofiisi re ni igba ti o ti ilu London to ti lo toju are re de ni eleekeji. Awon eku yii gba ofiisi naa lati odun to koja di odun yii, ni eyi to mu ki Aare maa pase lati ile. Eyin alarojinle, gbogbo wa la mo pe won ko bi iyalaya ati babanla eku dara lati gba ile lowo emi ati eyin sugbon won gba ofiisi lowo eni akoko lorileede yi.
Eranko keji ni MALUU, maluu ni awon agbe ni o n ba oko awon je nigba ti awon adamaluu n fipa ba iyawo awon lo, won si n pa awon to je oloko. Awon agbe pariwo fun ijoba ki won ma se je ki awon maluu maa rin kiri mo ki won ma baa ba gbogbo oko je. Eyi lo fa ija ti awon adamaluu fi bere si ni pa awon oloko. Titi di asiko ti mo n ko iroyin yii jo ni pipa eniyan si n lo lowo nitori maluu. Ni aye atijo, “opa kan pere ni Fulani fi n da igba maluu” bayii “ibon AK 47 ni Fulani fi n da maluu”.
Eranko keta ni EJO, ose to koja ni iroyin gbee pe obinrin osise JAMB, iyen ajo to n foju to sise idanwo asewole si Fasiti , dede ni ejo mi bilionu merindinlogoji naira (B36N). Ere ni gbogbo wa koko pee, a ni ko si eni to le laju sile so iru oro bee jade. Ojo keji ni awon eniyan bere si fi fidio ibi to ti soo naa ranse.
Eyin alarojinle gbogbo, obinrin yii mo pe ko si ohun to maa sele. A maa pariwo naa ni, a si maa dake. Oun ko ni akoko to maa se owo ilu maku-maku. Eni ti a ko le mu, Eledua ni a maa fi le lowo. Ere ori itage ati awada ako yii ko le lo lori opo eniyan ni kiakia. Ipade tun di ose to n bo lase Edumare.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú

Wọ́n ti taari Sunday Igboho sílé-ẹjọ́ ní Kotonú Fẹ́mi Akínṣọlá Àwọn àgbà ní bí ọ̀rọ̀ nlá k…