Home iroyin Ko si ija Fulani ni opopona Ibadan si Eko – Olopaa
iroyin - February 8, 2018

Ko si ija Fulani ni opopona Ibadan si Eko – Olopaa

“Iroyin eleje” kan n kaakiri ori foonu awon omo Naijiria lati ana ojo weside pe awon Fulani darandaran ti gba ijoba ni opopona masose Eko si Ibadan. Won si n pa eniyan bi eni pa eran, koda ti won ba pa eniyan tan, won a tun dana sun won.
Awon onise ibi yii tile lo gbe isele ijamba moto kan to waye ni nnkan bii odun marun-un seyin ti oko tanka to gbepo jona lasiko naa. Ni eyi to mu ki gbogbo oju ona dudu kira.
Agbenuso awon olopaa ni ipinle ogun, ogbeni Abimbola Oyeyemi ni o n ba awon oniroyin soro lonii ojo Alamiisi. O ni ki onikaluku maa ba ise oojo re lo pe ko sewu kankan. O ni gbogbo eto ati asepo to gbopan lo ti wa ni aarin awon Oba, Baale ati awon ijoba idagbasoke kookan.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́

Jàndùkú ya wọ iléeṣẹ́ rédíò Amúlùúdùn n’Íbàdàn, wọ́n ba ọ̀pọ̀ dúkìá jẹ́ Ọrẹ Òtítọ́jù Òkú k…