Ìjọba tí kò sí lọ́wọ́ àwọn Ọba ni kò jẹ́ kí ayé ó gún régé mọ́ – Oluwo
Oluwo ti ilu Iwo, Oba Abdul-Rasheed Adewale ni ohun ti ko je ki aye roju mo ko jina lati wa kiri. O ni ijoba ti ko si lowo awon Oba mo lo faa. O ni Oba nikan lo n ba Eledumare je oruko po ti awon wa je eni to wa laarin awon ara ilu ati Eledua. O ni awon ni Eledua fi gbogbo akoso ile aye le lowo, nitori pe Oba ni oko oso, oko aje ati oko elebo-loogun.
Ti eku ko ba ke bi eku mo, ti eye ko ke bi eye mo tabi omo eniyan ti ko fohun bi omo eniyan. Oba nikan lo mo ohun ti a n se. Oba nikan lo mo bi a se n be awon alale ti gbogbo nnkan si maa bere si ni tuba-tuse.
Oluwo pe akiyesi si asiko ti o je pe Oba lo n dari gbogbo nnkan ni ilu, o ni eyi to ba fe ru won loju, won mo bi won se n fi ese ile too, sugbon ti ko ri bee mo ni aye ode oni. Oluwo ni peluu bi o se ri yii naa, a ko gbodo kawo gbera, a ni lati kun won lowo naa ni nitori pe “Aafaa to ni iyan yoo mu, omo tire naa ko ni je tira”.
Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò
Igboho àtàwọn adarí OPC bẹ Aarẹ Ọ̀nà Kakanfo ilẹ̀ Yoruba wò Ọrẹ Òtítọ́jù Aja-fẹtọọ’m…