Home Orisirisi Atiku fi bi ija 2019 yoo s ri han
Orisirisi - November 29, 2017

Atiku fi bi ija 2019 yoo s ri han

 

Bi o se kuro ni APC da awuyewuye sile lotun-un losi

  • Se Tinubu mo si i ni?
  • Kin ni ero Saraki ati awon asofin yoku?
  • Nje Atiku le gbe Buhari sanle bi?

 

Igbese nla ti Igbakeji Aare tele, Alhaji Atiku Abubakar, gbe lose to lo, nipa kikuro ni egbe APC, ti fihan pe pipada sipo Aare Mohammadu Buhari ni odun 2017 ko le dab ii ki eniyan maa feran jeko.

Opo eniyan lo mo pe erongba Atiku ni lati di Aare. Bee, ko si aaye fun un ni APC bayii.  Sugbon ni ti PDP, awon n wa eni to gborin to le fun Buhari nija. Bee, idi niyii ti eni fe ku se pade eni ti yoo pa a.

Lati odun 1992 ni Atiku ti n pete ati di Aare Naijiria. Ninu ibo abele SDP, o ja raburabu lati bori MKO Abiola, ninu ibo abele to waye ni Jos.

Die naa ni MKO se gbe e sanle nigba na lohun.

Nigba ti PDP de ijoba ni 1999, Atiku ko fibo pe oun fe di Aare leyin Olusegun Obasanjo. Koda, bi o ba se se se, o fe ki Obasanjo koro nipo lai tojo. Iru erongba bee lo da wahala nla sile laarin oun ati Obasanjo, to fi di pe Obasanjo ko fe ri imi re laata ninu oselu mo.

Lasiko laasigbo APC naa, Atiku ba Buhari fa a , to si je pe, di oni olonii, opo oloselu lo wa ninu egbe oselu idakonko to ni.

Ohun ti awon amoye n so ni pe Atiku nikan ko lo da igbese kikuro ni APC gbe. Won ni oun ati awon oloselu kan ti ni jo hun kinni ohun.

Lara won ni awon asofin kan wa, ti awon eniyan si n rokan pe Bukola Saraki ati awon emewa re wa nibe.

Ibi ti ibeere wa ni pe, bi Atiku ba koju Buhari ni 2019, kin ni yoo sele?

Nje o le da PDP pada bo sipo?

Awon oludibo ni yoo dahun eyi. Sugbon awon nnkan miiran naa wa nibe. O nira lati oju ijoba to wa nipo bole. O seese ki ijoba Buhari bere sii ka awon esun kan an si i lese.

Ohun to tun wa tun n sele ni pe, awon eniyan yoo maa beere pe se  ijoba Buhari ti sise to lati je ki o di didibo fun pada?

Sugbon Atiku naa nko? Nije o kappa ati gbe Naijiria de ebute ogo? Nje iwa re dara to lati mu ki Naijiria yan an si ipo.

Bee, ibo ni Tinubu wa ninu oro yii? Loooto, o ti so pe ti Buhari ni oun si n se, sugbon lose to lo, Tinubu tun so pe ibo ni APC yoo fi yan ani ti yoo soju re ninu ijoba Aare.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…