Home Orisirisi Ohun nla ti Subomi Balogun se ninu aye Alex Ekwueme
Orisirisi - November 27, 2017

Ohun nla ti Subomi Balogun se ninu aye Alex Ekwueme

 

Bi eniyan sere, bi oluware sbi, gbogbo ree naa lo maa n wo iwe itan.

Igba ti Igbakeji Aare lasiko ijoba Alhaji Sheu Shagari Dokita Alex Ekwueme, ku la to mo pe awon isele nla kan se laarin won.

Koda, oro  naa je isele ojo pipe.

Ni nnkan bii ogota odun seyin ni Subomi Balogun jo n gbe legbe ara won ni Apapa, ni Ipinle Eko.

Awon mejeeji jo ko ile sibe ni.

Sugbon kop e ko jinna ni ogun Biafra wole.

Nigba ti ogun naa gbona janjan, awon omo Igbo salo si ilu won.

Opo awon omo Igbo to ni ile ni Eko naa ni eru n ba pe ile naa ti di ti elomiran.

Sugbon Subomi Balogun se nnkan nla fun Ekwueme lasiko naa.

O fi ile Ekwueme renti, o wa lo si aka-n-ti kan si banki. Gbogbo owo ti awon mehaya ile naa n san losu, losu, Subomi Balogun n ba Ekwueme ko owo naa si.

Nigba ti ogun pari leyin bii odun merin, awon omo Igbo pada si Eko.

Ekwueme ko tile mo pe oun a ba ile naa ni Apapa mo.

Sugbon leyin pe o ba ile re nibi to ko o si, Subomi Balogun tun ko gbogbo owo awon merenti fun un.

Igba ti Olorun wag be bi o se maa n se de, lasiko ti Subomi Balogun fe da ile ifowopamo FCMB sile ni Ekwueme di igbakeji Aare Shagri. Lojo kan ti won wa pade, o wa so wuyewuye si Ekwueme leti ohun to wa lokan re.

Bayii ni Ekwueme naa se se iranwo fun un pada, lori iwe ase banki naa, ti a n pe ni lanseesi.

Lanseesi naa ni banki naa n lo di oni olonii.

Ose to lo ni iroyin ja lule lati ilu London pe gbogbo ipa ti awon dokita sa lati ra emi Ekweme pada lo ja si pabo.

Naijiria ni won ti n se itoju re tele, ki won to gbe e lo si oke okun.

Ekwueme ni igbakeji Aare Sheu Shagari, ti won si jo se ijoba ni odun 1979 si 1983.

Opo eniyan, to fi mo Aare Mohammadu Buhari, awon gomina ati awon asofin ni won ki Ekwueme pe o digba o se.

Lasiko to n se igbakeji Shagari, aarin won da moran, to si je pe won ko ja nigba kookan.

Lasiko awon ijoba ologun naa, Ekwueme se iwon to le se pelu awon agbaagba miran, lati ri i pe ijoba tiwa-n-tiwa pada siluu.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…