Home iroyin Ẹ̀bùn EFCC dá wàhálà sílẹ̀
iroyin - November 15, 2017

Ẹ̀bùn EFCC dá wàhálà sílẹ̀

Yoruba bo, won ni “owo ni je mo ba o tan, osi ni n je ta ni mo o ri”. Ebun ti ajo EFCC maa n fun awon to ba sofofo awon to kowo ilu je ti di wahala bayii. Stephen Sunday ni oruko eni to tu asiri owo rogun-rogun ti awon ajo EFCC lo ko ni ile kan to wa ni nomba 15A, opopona Awolowo ni ilu Ikoyi l’Eko.

Ojo kin-in-ni osu kerin odun yii ni ogbeni Sunday ti tu asiri owo ti ajo Nigeria Intellligence Agency (NIA) ni awon ni awon ni owo naa. Ohun ti won fe fi iru owo to po to bee se ati idi ti won fi gba ile fun owo naa ko see salaye, ni eyi to gbase kuro lowo ogbeni Oke to je oga ileese naa.

Ni igba ti ajo EFCC wo ida ogorun-un iye to ye ki won fun eni to sofofo naa (Whistle blower), oju gbogbo aye wo owo naa. Apapo owo naa je Milionu egberin le aadota naira (N850M).

Iroyin ti a ko tii le fi idi ooto re mule koko gbe e pe owo naa ti fe ya arakunrin Stephen ni were, ti ajo EFCC si ti n se itoju re, koda iroyin naa gbee pe won ti na Milionu otalelugba-din-mewaa naira (N250M) lori ogun to n lo.

Opo ore lo ti jade pe awon mo si owo naa. Agbejoro Stephen Yakubu Galadima ni ki ajo EFCC ma se da enikankan won lohun rara. O ni iro ni won n pa. O ni awon kan ti won koko gbo nipa owo naa ti n seto bi won se maa lo digun jale owo naa ki ogbeni Stephen to sare lo so fun awon ajo EFCC.

Ona lati lowo kankan ko rorun. Agbejoro Stephen ni oun maa gba ile ejo lo ti won ko ba tete da onibaara oun lohun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…