Home iroyin NURTW ń gbéná wojú Fayose
iroyin - October 12, 2017

NURTW ń gbéná wojú Fayose

Awon ajo onimoto ti ipinle Ekiti ( NURTW) ni won n fa wahala pelu gomina Ayodele Fayose ti ipinle Ekiti. “Eru kan ni mu ni bu igba eru” ni Yoruba maa n wi. Okan ninu awon oloye ajo onimoto ti oruko re n je Ahmed Kolo ni awon iko Fayose ni o wa moto re ni iwakuwa ni igba ti gomina jade, eyi bi Fayose ninu, o si ni ki awon olopaa fi owo sinkun ofin muu pe o wa moto ni iwakuwa. Awon ajo onimoto ko ara wonn jo lati la gba arakunrin naa sile, Fayose ni ko buru, ki won jo bebe fun orikunkun to se si gomina.

Arakunrin yi ko jale pe oun ko sẹ gomina, nipa idi eyi, oun ko ni ebe kankan lati be enikankan. Eyi bi Fayose ninu pe iru afojudi wo niyi. O ni ki oro naa di ejo ki awon lo roo. Ahamo awon olopaa ni okunrin naa wa lati igba ti isele naa ti se. Eyi lo si fa iwode ti o ti ni owo dida ilu ru ninu. Awon ajo onimoto ni o lodi sofin Naijiria lati ti eniyan mole ju wakati merinlelogun lo. Awon ajo onimoto ni, gomina ko leto lati ti eniyan mole labe ofin, won ni ile ejo nikan lo lase lati se iru re.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…