Home ÀṢÀ ÀTI ÌṢE Orúkọ tí ó jẹ mọ́ ìdílé
ÀṢÀ ÀTI ÌṢE - October 2, 2017

Orúkọ tí ó jẹ mọ́ ìdílé

Yooba gba pe oruko omo ni ijanu omo.ldi niyi ti yooba fi maa n wa oruko ti o rewa so omo o won.Owuro kutukutu ni won n so omo loruko nile e yooba. Ojo keje ni won n fun obinrin ni oruko, ni igbagbo pe eegun meje ni o ni, nigba ti okunrin n gba oruko ni ojo kesan an, tori won gba pe mesan an ni eegun ti Eledaa fi sara  okunrin. Ojo kejo ni awon ibeji maa n gba oruko nile e yooba.
Awon nnkan ti a fi n so omo loruko niwonyi, obi, orogbo, odidi ataare, omi tutu, eja aaro, eku, oyin, iyo, epo pupa, oti ibile, Ireke, oyin, aadun, owo.(abbl)
Gbogbo awon nnkan wonyi ni won maa n fi i gbadura lasiko isomoloruko, nigba ti tebi tara, ore ati ojulumo ba wa ni ikale ,ti koowa yoo si maa se (ase)
Idile kookan nigba iwase , maa n so omo loruko nilanaa esin ti won n sin.
Apere: ( Idile onifa) Odubiyii, Faleti,Dopemu, Opewale.
(Elesu) Esuronke, Esubiyii, Esukemi.
(Oloogun) Ogunmola, Oguntuase,Ogunde,  Ogunrinola.
(Sanpona)Obafemi, Anibaba, Babayemi
(Olobatala) Aborisade, Efusetan,Orisatola Bamgbala.
(Sango)Sangokunle, Sangodahunsi, Sangotola.
(Olosun) Osunfunke, Osunrinu, Osugbekun.
(Oloya) Oyatoki, Oyatola, Oyatoke.
Bi o tile je pe, olaju ti mu ki won maa yi awon oruko wonyi pada si ti igbalode, sibe, itumo awon oruko naa ninu idile kookan ati esin ibile won si ni itumo ti o yanranti. Yato si awon oruko agbelero ti awon eeyan kan n so omo won .Bi won se wa n sojukokoro oruko awon oyinbo amunileru yii to, igbesi aye e won ko besue ju awon ti o n joruko abiso ninu esin ibile won. Teni n teni, Eeyan to ba mo itumo asa abinibi i re, yoo gbe laruge, yoo daabo bo, yoo si  so o di amuyangan nibi gbogbo. Sugbon omo ti ko ba ipele iya e, iwon ni ki e bu u  bi o ba si aso ro. Idile tirufe onitoun ti wa ni e se beere. Ire o.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…