Home ÀRÒJINLẸ̀ Ìbọn ti pọ̀ jù ní Nàìjíríà
ÀRÒJINLẸ̀ - October 2, 2017

Ìbọn ti pọ̀ jù ní Nàìjíríà

Hausa n pale ogun mo, orisa ma je ko tenu mi jade, Igbo n pale ogun mo, orisa ma je ko tenu mi boode, Yoruba n pale ogun mo, orisa ma je ko tenu mi jade. Awon eya miran lo n pale ogun mo, orisa ma je ko tenu mi boode. Abi awon alijonnu lo n pale ogun mo, orisa ma je ko tenu mi boode.

Eyin ololufe iwe IROYIN OWURO, paapaa julo eyin ayanfe abala yii. A ku ojo meta, a ku ilu yii, Eledua ko ni je ki aburu o kangun si wa tebi-tara. Gbogbo awa omo Naijiria ti a ba maa n ka iwe iroyin tabi gbo iroyin ni a maa ti mo pe osoose tabi osoosu ni awon ajo asobode (Customs) n gbese le onirunru ibon ogun ni bode to wo Naijiria.

Ti a ko ba nii paro tabi se afikun, ibon ti awon Customs ti gba lodun yii nikan le ni egberun meji. Iye ti o yo gba ori ile wole ko lonka. Gbogbo awon ti asobode yii gba, kin ni won fe fi se? Se won fe danu sun won ni abi pin-in fun awon ologun wa?  Owo awon ibon yii won de bi wi pe, ko si eyi towo re din ni irinwo naira (N400).

Ibeere arojinle miran ni pe, awon wo lo n ko awon ibon yii wole? Orileede wo ni awon ibon naa ti n wa? Ti eru ba n bo lori omi, won maa n ko ilu to ti n bo ati ilu to n lo si ara kontena naa. Kin lo de ti awon ajo yii ko je ki aye mo ibi ti awon ibon naa ti n wa. Eru ko si le maa bo lati oke okun, ki won ma se ko ibi to n lo ati eni to maa gbaa si ibi kan, kin lo de ti awon ajo yii ko je ki a mo awon ti won fi eru ibon ranse si.

Oro Naijiria, opo igba ni a maa n fi “ete sile maa pa lapalapa”. Awon olopaa n ba won ja pe won ko pe awon si iwadii awon to ni ibon. Ariyanjiyan yii tun le gba ojulowo ise naa lowo wa, awon kan ti bere si ni gbe ofin jade pe awon Customs ko lase lati da iwadii se, awon kan ni won le da se ti won ko ba ni igbagbo ninu olopaa.

Se awon eya lo n ko ibon wole ni abi esin abi awon aladaani? Kin ni won si fe fi se? Bawo ni ibon se po to bayii ni orileede yi? Nje a tile ni awon ajo to n foju to eleyii rara?

Gbogbo awon nnkan wonyi ni won ko fi aaye gba ni awon orileede to ti goke agba. Gbogbo orileede to ba tun fe goke gbodo le ni ikawo lori ohun ija oloro gbogbo to n wo ilu re. O ye ki ofin to maa de ibon ti ko ni iwe ase wa. O ye ki ofin to maa de awon imura to ni obe ati ohun ija oloro miran naa wa. Igbayi ni alaafia to le joba ni ilu to loba to si ni ijoye.

Ibere ija laa mo, enikan kii mo ipari re. Ogun o si da bi iyan tabi amala. Gbogbo awon omo to yo tan ti won n wa bekun-bekun, e ba mi so fun won pe ija ogun o dabi ALUTA ileeewe.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…