Home iroyin Fayose kéde láti du ipò Ààrẹ ní ọdún 2019
iroyin - September 28, 2017

Fayose kéde láti du ipò Ààrẹ ní ọdún 2019

Gomina ipinle Ekiti, Oloye Ayodele Fayose kede lati du ipo Aare Naijiria ni odun 2019 labe egbe oselu PDP. O ti to bii ojo meloo kan ti Fayose ti n soo bi ere bi ere pe oun maa dije du ipo Aare Naijiria sugbon ti opo eniyan ni ko seese.

Oni yii ni gomina naa jade si ita gbangban, ti o si pe awon oniroyin pe, oun maa du ipo Aare pelu enikeni to ba jade. O ni “n ko le wa ku, ko ni je oye ile baba re”. O ni iberu ni o n se opo eniyan ni ilu yii, o ni sugbon ni ti oun, ko sojo ni oro oun gege bi opo eniyan se mo.

Awon oniroyin beere pe bawo lo se maa jawe olubori nigba ti egbe re ko fowo sii?, o ni ko si oun to jo fowo sii tabi maa fowo sii. O ni ko tii ye ki won fowo sii lati ibere pepe ti won ba fe see daadaa. O ni n se lo ye ki won maa woran, ti asiko ba wa to, ko seni to maa so fun won ti won fi maa fowo ati gbogbo ara sii.

Fayose tun ni ti oun ko ba se oun ti oun se yii, o seese ki a ma se ri eni to maa dije du ipo Aare naa ni odun 2019.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…