Home ÀRÒJINLẸ̀ Buhari ati Atiku 2019
ÀRÒJINLẸ̀ - September 16, 2017

Buhari ati Atiku 2019

Ko pe odun meji mo bayii lati di ibo opo gomina ati baba won tii se Aare. Yoruba bo, won ni “o n bo, o n bo awon laa dee dee”.Eyi lo difa fun gbogbo awon to ni ife lati dije ni odun 2019 lati tete bere si ni mura sii bayii. Bi kuru-kere se n lo ni awon ipinle naa ni ti Aare n lo.

Ko si ariyanjiyan ninu egbe APC pe nibo ni Aare ti maa jade. Gbogbo egbe lo mo pe lati ile Hausa naa ni. Gege bi ofin ile wa, aaye wa fun eniyan lati sejoba ni eemeji tii se odun mejo. Buhari n pari odun merin akoko bayii. Kin lo wa de ti kuru-kere tun fi wa fun ipo Aare ninu egbe kan naa?

Aisan to se Aare ni enu ojo meta yii ti je ki igbakeji Aare Olusegun Obasanjo, iyen Atiku Abubarkar woo pe oun ni aaye naa tun to si. Loooto ni pe ko tii jade si ita gbangba maa polongo ibo, sugbon gbogbo isesi ati irinsi re ni awon eniyan n ka. Yato fun pe awon minisita Buhari kookan gan-an ti soo sita. Oun gan-an ti ko gbogbo ara sii.

Atiku ti woo pe awon jo dije du ipo naa ni lodun 2015 ki kadara to se Buhari loore. “Awon omoran tii moyun igbin ninu ikarahun” si ti n ba Atiku si ojo ori re pe, o maa pe odun metalelaadorin (73years) ni odun 2019. Ni eyi to tumo si pe ti kinni naa ko ba ti ja moo lowo ni odun naa, ko yaa gba pe kadara oun ko si nibe.

Gege bi ajagun-fehinti ti Atiku naa je, o n see ni ibi to ba le laa ba omokunrin, gbogbo ibi to ye ko rin si ni o ti tete see ni “atookere ni oloju jinjin ti n mekun sun”. Awon kan tile ni awon kefin re ni Eko peluu Asiwaju Bola Tinubu ati Babatunde Raji Fasola.

“Adake ma fohun, Eledua nikan lo kuku mo teni to n se”. Buhari ko kuku ba enikankan soro lori odun 2019. O see ni ohun ti a ba ba lo oju ogun laa koju mo. Ko tii beni kankan soro lori ibo odun naa.

Olorun nikan lo kuku mo ohun ti enikankan ko mo, pelu adura ati aawe awon ara ilu to fe ooto. Won ni Buhari naa ni awon n fe, bi ko tile se nnkan miran, bo je igbogun ti iwa ibaje nikan, o to ki eniyan ko gbogbo ibo re fun un. Nipa idi eyi, inu opo eniyan maa baje ti won ba gbo pe Buhari ko ni dije ni odun 2019.

Bi gbogbo re si se n lo yii, ti egbe APC ba ko lati gbe ipo naa fun Atiku, o seeese ki egbe miran ya lati ara egbe APC, nitori opo eniyan lo n so pe Atiku ti pinnu lokan re lati dije ni abe bi o se wu ki o ri.

Hun un! Bi ikun lo loko, bi takute ni, ipade di odun 2019.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…