Okunrin to la odo iyan mo oyinbo lori ni Ikorodu wo gau
Okunrin kan to se oyinbo kan lese ni Ikorodu, ni Ipinle Eko, laipe yii ti wa ni panpe awon olopaa bayii.
Odo iyan ni okunrin naa ti oruko re n je Orabe Leo la mo oyinbo naa, Robert Rob Wheelers, lori, to si je pe Olorun lo yo o.
Leo so fun awon olopaa pe oyinbo naa, ti won jo n sise papo tele, se ileri lati fun oun lowo, sugbon ko se bee.
O ni gbogbo aajo ti oun se ko je, eyi lo bi oun ninu ti oun fi la odo iyan mo o lori.
Alukoro awon olopaa, Arabinrin Dolapo Badmus, lo se alaye oro yii ninu atejade kan.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…