Home iroyin Ayé níkà! Fasayo àti Abdulrafiu gé ọmú ọmọ College of Education mẹ́ta torí N15M
iroyin - September 10, 2017

Ayé níkà! Fasayo àti Abdulrafiu gé ọmú ọmọ College of Education mẹ́ta torí N15M

 

Ti a ba ti n sun ti a n ji, o ye ki a maa gbadura pe ki Olorun ma je ka rin lojo ebi n pona, ki a ma si pade arinnako.

Awon omo ile iwe Adeyemi College of Education, Ondo, meta pade iru arinnako bee laipe yii, nigba ti won bo s’owo awon gbomogbomo.

Won ji won gbe, won si ge oyan won, won ge owo won, won wa lo sin won si aginju igbo leyin tie mi ti bo lara won.

Oruko meji ninu awon omo naa ni Blessing Oladepo ati Mary Oluwasemire, nigba ti won ko tii te oruko eni keta sita.

Iroyin fi ye ni pe awon osika eniyan naa ni John Adenitire, ti adape re n je Emir; Fasayo Fasanu, ti adape re n je Abore ati babalawo kan ti won pe oruko re ni Alfa Abdulrafiu Tijani.

Ni bayii, owo awon olopaa Ipinle Ondo ti te awon odaran yii, sugbon lopo igba, ki Olorun to mu osika, osika a ti ba ohun to dara je. Awon karanbaani eniyan naa ti ran omo ile iwe giga sorun osan gangan.

Tijani ati awon to ku ni eni kan ti oruko re n je Sile lo gbe ise fun awon.

O so fun won pe oun yoo fun won ni milionu marun-un lori omo kookan, eyi to tumo si pe milionu meedogun ni awon meteeta fe gba.

Won wa ni awon ko tii ri owo naa gba lowo Sile.

A si gbo pe Sile tin a papa bora bayii.

Oga Olopaa ni Ipinle Ondo, Alagba Gbenga Adeyanju, se alaye pe iwadii si n lo lowo lori oro naa, nigba ti awon gbomogbomo naa si wa ni ahamo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…