Home Orisirisi Musiliu Haruna Ishola yo suti ete si awon to paro pe Awujale ti ku
Orisirisi - September 9, 2017

Musiliu Haruna Ishola yo suti ete si awon to paro pe Awujale ti ku

 

Akorin apala ti a mo si Musiliu Haruna Ishola dan mewaa wo ni Ijebu Ode ni ojo Sunday, nigba ti Ojude Oba n lo lowo.

Bi o tile je pe opo osere aguda, dundun ati sekere lo lo gbe awon Regberegbe laruge lojo naa, Musiliu ni awon to seto ayajo odun naa moomo pe, t si je pe o se bi baba re, iyen Oloogbe Haruna Ishola, se maa n se.

Bi o se n korin apala ti baba re, bee naa lo ko ti igbalode. K’oda, o tun ko orin ti Qdot, iyen asesejade alapala kan to korin ‘Mo fe s’ase’.

Lati aaro to ti bere ere lo ti n ki Awujale ni mesan-an mewaa, ti ori gbogbo omo Ijebu si n wu.

Ninu awon orin kan to ko fun Awujale, o bu awon to gbe enu ni igbekugbee laipe yii, nigba ti won ni lapalapa, ki a ma daruko Awujale, ti ku.

Musiliu ni ki won sinmi ‘rumour’, ki won fi ete oke bo tile, o ni ki wa wo eni ti won n so isokuso nipa re bo se jokoo ninu ola nla, ti gbogbo eniyan si n wari fun un.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…