Home iroyin Ọwọ́ tẹ “man ‘o war” tó jí Okada
iroyin - September 6, 2017

Ọwọ́ tẹ “man ‘o war” tó jí Okada

Ninu iroyin wa kan ti a kọ lọjọ to pẹ diẹ nipa iwa awọn  “Man ‘o war” to wa ni agbegbe Iṣawo ni ilu Ikorodu nipa pe ki ijọba mai ti ro wọn lagbara lati di ẹṣọ ologun. Iroyin miran ti a tun gbo ni pe lọjọ Aje to kọja ni iroyin gbee pe ajọ to n moju to ayika fi ipa ofin mu arakunrin “Man ‘o’ war” kan nitori o ji ọkada ti ajọ naa gba lọwọ ọlọkada ti o tapa si ofin ni agbegbe Berger.

Ẹni to jẹ ka mọ eyi ni Ọgbẹni Wilson Alaba. O ni arakunrin Ọlajide Felix to jẹ “Man ‘o’ war” wa lara awọn ti wọn yan ko ba  awọn ajọ ayika ṣiṣẹ nipa fifipa ofin mu ẹni to ba tapa si ofin irinna. Ni ọjọ ti wọn sọ pe o ji ọkada yi, wọn ti pari iṣẹ wọn si ti gbe awọn ọkada ti wọn gba lọ si ile-iṣẹ ajọ ayika amọ nigba ti wọn ka awọn ọkada naa ni wọn rii pe ko pe iyẹn ti wọn gba. Ifimu finlẹ ti wọn ṣe ni o fihan pe arakunrin Felix ni o gbe ọkada naa.

Nigba ti wọn fi ọrọ wa arakunrin Felix lẹnu wo, o jẹwọ pe loootọ ni pe oun loun ji ọkada naa, oun si fẹ maa fi ṣiṣẹ ni. Ọgbẹni Felix to le ni ọmọ ọgbọn ọdun lo n bẹbẹ ki wọn ṣe oun jẹjẹ, ki wọn si dariji oun.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…