Home iroyin Olori esin Islam digbo lu Fayose lori lawani lemoomu to we lojo Ileya
iroyin - September 6, 2017

Olori esin Islam digbo lu Fayose lori lawani lemoomu to we lojo Ileya

 

Olori esin Musulumi kan, Ojogbon Ishaq Akintola, ti so oko oro si Gomina Ayodele Fayose ti Ipinle Ekiti, lori bi o se wo aso lemoomu lo si Yidi lojo Ileya to lo.

Aso aafa nla kenke ni Fayose wo ni Ado-Ekiti lojo naa, to si we lawani babatutu.

Ninu atejade kan ti Akintola, to je Aare ajo kan to n ja ajagbara fun esin Musulumi, iyen Muslims Rights Concern, se so, o ni eni ti ko ba je lemoomu ko letoo lati wo iru aso bee, ki a ma wule so eni ti kii se Musulumi.

Akintola ni o dabi ki eniyan lasan wo aso alagba soosi ni, laise pe o je olori ijo.

O fi kun un pe Fayose se ohun to balumo nipa siso oro oselu nibi tiwon ti n kirun Ileya naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…