Home Orisirisi Ogoji odun ni Owa Obokun fi ju Ooni lo, sibesibe, Owa ni eni iyi ni Ooni je
Orisirisi - September 6, 2017

Ogoji odun ni Owa Obokun fi ju Ooni lo, sibesibe, Owa ni eni iyi ni Ooni je

 

 

Owa Obokun ti ile Ijesa, Oba Adekunle Aromolaran, ti se apejuwe Ooni Ife, Oba Oba Adeyeye Ogunwusi, gege bii eni iyi ati eni eye ti gbogbo omo Yoruba gbodo maa gbe gege.

Ni ti ojo ori, igi imu jinna sori, nitori o fee to ogoji odun ti Oba Aromolaran fi ju Oba Ogunwusi lo.

Sibesibe, Owa kan saara si Ooni lasiko to se abewo pataki si i ni aafin re ni Ife.

Oba naa kan saara si Ooni lori igbese irepo laarin awon oba to n gbe, ati awon ise idagbasoke ilu to n se.

Bakan naa, Owa se alaye pe oun lo si aafin Ife lati pe Ooni si ojo ibi ologorin odun oun to maa waye ninu osu kewaa.

Oba Ogunwusi dunnu si abewo naa, o si gbadura ki Olorun tubo maa fun Owa l’okun ati alaafia.

Eemeji ni Ooni naa ti be Owa wo ni Ilesa lati nnkan bii odun meji to ti j’oba.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…