Home Orisirisi Ìrọ̀lẹ́ ayé dé, Ọmọbìnrin ọdún mẹ́wàá nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn
Orisirisi - September 4, 2017

Ìrọ̀lẹ́ ayé dé, Ọmọbìnrin ọdún mẹ́wàá nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn

Ìrọ̀lẹ́ ayé dé, Ọmọbìnrin ọdún mẹ́wàá nínú ẹgbẹ́ òkùnkùn

Ana ojo keta, osu kesan-an odun yii ni asiri awon odomodebinrin ti ojo ori won ko ju mewaa si metala lo pelu awon mesan-an miran tu si owo awon olopaa ipinle Ogun.

Mama okan ninu won lo kefin pe omo oun maa n jade ni ale ti ko si eni to ran an nise, o hale mo omo naa to fi jewo bi awon se maa n se ipade ati ibi ti awon ti maa n see, koda o je ki iya naa mo ojo ati ibi ibura fun awon ni ale ojo ti owo awon agbofinro te won.

Gbogbo awon ti owo te naa je olugba Mosunmore ni Kobape ni ilu Abeokuta. Oga olopaa Sheu Alao ni o siwaju iko to lo fi owo sinkun ofin mu won nigba ti komisona olopaa ipinle Ogun, Ogbeni Ahmed Illiyasu naa jeri si oro naa pe okan ninu awon obi awon omo naa lo ta Baale adugbo naa lolobo ki Baale to kan si awon, ti owo fi te awon omo buruku naa.

Oruko egbe okunkun won naa ni “Penalty Guys”. Oga won ni Tunde Adio to je omo odun mokandinlogun. Tunde yii naa ni ogbeni Tosin kan lo pe oun si egbe naa. Igbakeji Tunde ni Silas Sunday ti owo awon olopaa tun te lojo naa. Won ni awon ni aso ti awon maa n wo ti opo ko ki n fi n mo pe egbe okunkun n awon, aso naa maa n ni akole “Penalty Guys” lara. Tunde ni eyi wa ninu ohun ti awon omo keekeke fi nife si egbe okunkun naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…