Home iroyin Kannakánná p’ọmọ ẹ̀gà: Olúbàdàn kò lọ bá Ajimobi kí Yídì pọ̀
iroyin - September 2, 2017

Kannakánná p’ọmọ ẹ̀gà: Olúbàdàn kò lọ bá Ajimobi kí Yídì pọ̀

. N ko se keeta Olubadan ati Ladoja – Ajimobi

Olubadan ti Ibadan, Oba Saliu Adetunji, fi ibinu re si Gomina Abiola Ajimobi ti Ipinle Oyo han lanaa ojo Odun Ileya nigba to ko lati darapo mo gomina ati awon Musulumi yoku lati kirun ni Yidi Agodi.

Dipo bee, Olubadan ati awon Mogaji Ibadan korajo, ti won si kirun ni aafin re.

Eyi je ilodi si bi ijoba Ajimobi se gbe awon oba mokanlelogun miiran dide ni Ibadan.

Ki ojo odun to pe ni awon Mogaji ti da Kabiyesi nimoran pe ko ma lo darapo mo Ajimobi nitori aabo re.

Sugbon nigbati Ajimobi n soro lasiko ikirun odun naa, o ni oun ko ba Olubadan ja. O ni oun si setan lati maa bowo fun un. O ni atunto ti oun se, fun idagbasoke Ibadan ni, ati pe ko ni nnkan kan se pelu ola Olubadan, tori bi won se n yan Olubadan naa ni won yoo si maa yan an.

O wa fi kun un pe awon oloselu kan ni won go sabe Kabiyesi, ti won si n da ede aiyede sile.

Koda, gomina ni oun ko se atunto naa lati dubuu Senito Rashidi Ladoja pe boya ko ma lee di Olubadan.

O ni eni to ba n ge igi dina fun omolakeji, oun naa ko ni ni ilosiwaju.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…