Home ERÉ ÌDÁRAYÁ Odion Ighalo àti Mikel ju bọ́ọ̀lù sílé Cameroon
ERÉ ÌDÁRAYÁ - September 1, 2017

Odion Ighalo àti Mikel ju bọ́ọ̀lù sílé Cameroon

Awon egbe agbaboolu Super Eagles n fun Naijiria ni ebun pataki fun odun ileya lowolowo yii.

Ninu boolu fun idije World Cup ti won n gbe ni Uyo, ni Ipinle Akwa Ibom, won ti gba ami ayo meji wole Cameroon, ti awon ko si tii ta putu.

Odion Ighalo lo koko fa awon yo, nigba to ge agbeyin fun Cameroon, to si so boolu si awon kalo. Gee ni ariwo ta.

Mikel naa fakoyo leyin o reyin.

Bi majiiki lo ri nigba to sare ta boolu kan to n bo lati corner wole.

Goli Gameroon gan-an ko mo ohun ti o n lo, o kan yaju lati ri i pe a boolu ti wo yara oun ni.

Idije naa si n lo lowo, tori abala akoko ni goolu mejeji ti wa, ti abala keji si sese bere.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…