Allahu Akbar! Ọmọ Naijiria márùn-ún ti kú sí Mecca
Kadara lau!
Marun-un ninu awon omo Naijiria to wa ni Haaji ti odun yii ni won ti ku ni Mecca o.
Eyi sese di mimo lati owo Alaga Igbimo Haahi ni orile-ede yii, iyen National Hajj Commission, Alhaji Abdullahi Muhammed.
Sugbon ko tii so oruko awon ti oro kan.
O ni awon ko le tii se bee tori awon gbodo koko so oro isele naa fun awon molebi eni oro kan.
Ki Olorun fori jin awon ti olojo de ba.
OTOLORIN YORUBA: Itumo owe ‘Omo go, e ni o ma ku, pelu FIDIO
Okan lara awon owe Yoruba pataki ni ‘Omo go, e ni ko ma ku, kin lo tun n pa omo to j…