Home iroyin Ẹ jẹ́ kí Diezani wá jẹ́jọ́ ní Nàìjíríà – “Concerned Nigerians”
iroyin - August 28, 2017

Ẹ jẹ́ kí Diezani wá jẹ́jọ́ ní Nàìjíríà – “Concerned Nigerians”

Awon ajo ti kii se ti ijoba ti won pe awon egbe won ni “Concerned Nigerians” ni ki ajo EFCC lo gbogbo agbara won lati gbe Diezani Alison-Madueke wa Naijiria lati wa jejo. Diezani yii ni minisita epo petiro ni asiko isejoba Goodluck Jonathan.

Oun kan naa ni won n gbe kaakiri ni ilu Oyinbo nipa owo rogun-rogun to ko je ni igba isejoba naa. Bi ijoba Naijiria se n gba ile ni won n gbese le ile ti ko mo niye ti arabinrin naa fi owo ijoba ra. Pelu re naa, awon omo Naijiria tile fe rii ki won bi leere oun to ri lobe to fi waro owo.  Nitori pe owo naa ti po ju fun enikan lati ko je. Owo naa ju owo eto isuna odidi odun kan lo ni Naijiria.

Awon  “Concerned Nigerians” yii naa ni won se iwode odidi ose kan gbako ni ilu Abuja, ti won ni ki Aare Mohammadu Buhari kowe fi ipo sile tabi ko wale. Ose keji ko pari ti Aare fi wale, awon kan naa ni won ti tun dide si Daezani bayii ni olu ileese ajo EFCC to wa l’Abuja.

Chalse Oputa ti gbogbo aye mo si chaley boy pelu Deji Adeyanju ni won n dari egbe naa. Ogbeni Peter Aremu ni o jade gege bii asoju fun awon ajo EFCC ni igba ti awon ajo yii wode de iwaju ofiisi won. Peter ni ki awon egbe yii lo ni suuru, o ni gbogbo nnkan lo ni igbese, awon si gbodo telee. O ni ti won ko ba gbagbe, gbogbo owo to ko je ni ilu yii ni awon ti te ranse si gbogbo omo Naijiria.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…