Home ÀRÒJINLẸ̀ Ìfẹ Buhari
ÀRÒJINLẸ̀ - August 26, 2017

Ìfẹ Buhari

Yorùbá bọ̀ “wọ́n ní ẹni tó ràjò tí kò tètè dé ló jẹ́ kí aráyé ó robi ròó”. Eyi lo sẹlẹ si Aarẹ Mohammadu Buhari. Aisan ti Aare lọ wo ni ilu Oba fun ojo merinlelogorun –un fa orisiirisii awuye-wuye ki o to de. Orisiirisii iwode, eyi to ta koo ati eyi to gbe leyin re. Aroye naa wa lori bi awon eniyan se lo n kii ni London.

Gbogbo aworan ati fidio ti won n fi ranse lati London ni awon eniyan kan ni ayederu ni. Awon kan ni ko le soro mo, ko da eniyan mo ati orisiirisii nnkan buruku miran. Awon to sun mo Aare peki-peki ni aisan naa ko ki n se oju lasan. Koda iyawo re gan-an so ohun to jo bee ni igba kan pe “gbogbo awon nnkan oloro to n da oko oun laamu ni Olorun maa mu ni igba to ba de”.  Buhari gan-an ni oun ko tii se iru aisan bee ri lati igba ti oun ti daye. Ko rorun ni ilu yii lati gbogun ti awon onijibiti. Gbogbo wa la mo oun ti oju oloogbe arabinrin Dora Akuyuli,olori ajo NAFDAC ri nitori pe o n gbogun ti awon onise ibi to n ko oogun ayederu wole.

Ija akinkanju ni Buhari n ja, ko rorun lati gbogun ti awon onijibiti. Ko si ohun buruku ti won le ni won lo fun Buhari ti a ko ni gbagbo. Gbogbo owo to ye ki emi ati eyin maa fi sola ni awon okanjua ti ko ni akoju. Oro won ko ye mi, se won fe maa je owo ni abi muu, abi won fe maa sun sori re, abi won fe fi maa ranso, abi won fe fi se moto? Emi o tile mo ohun ti enikan ko se ri ti awon odaju yii fe maa fi owo se. Owo ti won ni Daezani Alison-Madueke ko soro gbagbo fun omoniyan ki a ma sese wa so obinrin-binrin. Owo to ju owo isuna orileede yii lo lodun kan. Bawo lo se rii ko gan-an to fi po to bee? Ejo maa n be lorun ooo.

Ife Buhari lo si n gbe wa ro ni ilu bayii. Ara ilu si ni igbagbo to po ninu Buhari, eyi lo si fa ero repete lojo to wolu. Ti a ko ba ni paro fun ara wa, ebi wa ni ilu sugbon ife ti ara ilu ni lo je ki a maa panu mo ebi naa. Asiri awon ika to ko owo rogun-rogun je to n tu naa je ki a maa woo pe, abajo ti ilu fi le. Igbagbọ yii dabi eyi ti a ni si Oloogbe M.K.o Abiola ni igba aye re, bi o se wole ibo ni ara ti de gbogbo wa. Wọn ni miliki ati mọto ijapa Abiola ti de si oju omi. Ọkan gbogbo wa ti bale ki awon abani-layọ-jẹ to da esi ibo naa duro. Wọn ni ko dara ki gbogbo wa maa gbadun. Ẹjọ maa n bẹ lọrun o.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…