Baale Babatunde Saliu Dada fi àmì ẹ̀yẹ dá olórí Hausa àti àwọn ènìyàn míràn lọ́lá
Ife ni iwe mimo pe ni “akoja ofin” Eyii je ohun ti o fi oju han gedegbe ni Ogunjo Osu Kejo eyii n ni Ojo Aiku 20/8/2017 ni Ilu Okeodo ti Ijoba Ibile Alimosho Agbado OkeOdo nibi ti Baale Babatunde Saliu Dada ti fi ife tooto han si gbogbo eya ti O fi Oke Odo se ibugbe tabi se karakata.
Ohun iwuri nlanla ni o je fun gbogbo awon eniyan nigba ti eya Hausa koko fi ere idaraya ati asa won side eto naa, Olori awon Arewa yii Alhaji Ado Shuaibu Dansudu fi to IROYIN OWURO leti wi pe odun kejilelogbon niyi ti oun ti wa ni Ilu Oke Odo pelu irepo laarin gbogbo eya ati idanmoran laarin awon ati Baale . Bi o tile je pe” eniyan kii rin ki ori o ma mi”. ede aiyede ko le sai ma waye sibe awon mo bi awon se n yanju re ni aarin ara awon pelu ifowosowopo Baale ati awon ara Ilu lapapo.
Lara awon ti won peju pese sibi odun isese oko odo ni Baale Arigbanla : Oloye Oladele Falohun Akinlabi , asoju Alaga LCDA Hon. Adisa, Oloye oni fila funfun lati Ilu Eko, awon oniroyin lati BOND FM, awon Oloye Oke Odo , awon iyaloja ,babaloja, olori egbe onimoto ti Alimoso, awon agbofinro ati awon eniyan pataki lawujo. Ninu aisi akoko fun oro, sibe Olori Oluwatooyin Dada fi to IROYIN OWURO leti pe “ Isese maa n tun Ilu se ni, o si maa n ko ikolo Ilu ati Orileede pada ati wi pe Isese nipa ti “Oro ki ke” maa n ko ipaya baa awon onise ibi ni sise” Lakotan Olori Oluwatooyin ati awon omo Ilu Oke Odo ti IROYIN OWURO fi oro wa lenu wo n ro Ijoba Ipinle Eko labe akoso Gomina Akinwunmi Ambode lati fi ojurere wo Baale Oke Odo nitori asiko ti to fun Ilu Oke Odo lati gbade!
Ki ayajo odun Isese ati “Oke Odo Day” to wa si opin, Baale Saliu Dada fi ami eye da olori awon Arewa, awon Oba Hausa lokan-o-jokan ati awon omo Ilu lola. Lakotan, Oko Ilu wa dupe pupo lowo Ijoba ipinle, ijoba ibile, awon to peju pese sibi ajoyo “ Oke Odo Day” ati odun Isese todun yii, paapaa julo alaga eto naa Omoba Adejumo ati awon iko re. Baale wa ro gbogbo awon olodun wi pe “Ki won fi eso se nitori eso pele ni ejo n gun igi agbon”
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…