Home iroyin Sultan kéde ọjọ́ ọdún Iléyá
iroyin - August 23, 2017

Sultan kéde ọjọ́ ọdún Iléyá

Sultan ti Sokoto, Alhaji Muhammadu Sa’ad 11, ti kede ojo kinni, osu kesan-an gege bi ojo odun Id-el kabir ti Yoruba maa n pe ni odun Ileya.

Odun idunnu ni odun Ileya je fun awon elesin Musulumi nitori pe, Allah siju aanu wo esin naa lo se fi eran agbo paaro omo akobi ti gbogbo Musulumi ko ba maa pa ni odoodun.

Eyi naa lo si faa ti o fi je pe eran agbo lo wopo ti awon Aafaa si gba pe o ni esan rere (Laada) ju ninu awon nnkan osin lati fi se odun Ileya.

Oni naa ni won ni ojo Ileya ku ojo mewaa gege bi onka oju orun ti won maa n wo. Sultan si ro awon Musuumi jake-jado Naijiria lati kun fun aawe ati adura pelu ise rere fun gbogbo ojo mewewaa naa.

Sultan ni bee naa si ni irokeke nile Allah naa maa lo lowo ni ilu Meka ati Medina pelu awon Musulumi to ba ise Haji lo si ibe. O tun fi asiko naa parowa isokan Naijiria, o ni Olorun ko se asise lati da wa po gege bi orileede kan.

 

 

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…