Home iroyin Àwọn ológun ló da ètò Nàìjíríà rú – Prof Banji Akintoye
iroyin - August 23, 2017

Àwọn ológun ló da ètò Nàìjíríà rú – Prof Banji Akintoye

Ero to dara ni awon baba nla wa ni fun Naijiria ni ibere pepe. Okan naa si ni Naijiria amo onikalauku gbodo lagbara lati tun agbegbe re se. Eyi ni a fi gba ominira ni odun 1960 ti a si loo titi di odun 1966 ki o to di pe awon ologun bere ijoba.

Ariwo atunto ti a si n pa, ti a ko ba daa isejoba ilu yii pada si bo se wa tele, a je pe iro ni a n pa fun ara wa. Gbogbo agbara lati se ilu gbodo pada si odo awon elekun-jekun, eyi to ba si to si ijoba apapo, won maa fun un.

Ojogbon Banji Akintoye lo n salaye yii fun awon oniroyin lori telifison ni ale ojo Weside. O ni oro atunto ti fere maa daru mo awon eniyan kan lowo, o ni ko si ye ko daru nitori pe ko pin Naijiria si otooto bi awon kan se nii lokan. O ni sise atunto ilu ko ni ki onikaluku maa pada si ekun re tabi ki awon eya kan ma se rin ni agbegbe kan. O ni dida agbara owo ati oro pada fun awon to nii ni akoko ninu atunto.

Ojogbon yii ni, atunto gidi ti awon n pariwo ko ni nnkankan se pelu esin tabi eya, ko la ogun tabi ote lo rara.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…