Home Orisirisi Ààrẹ Buhari sèpàdé pàjáwìrì nítorí ètò ààbò
Orisirisi - August 22, 2017

Ààrẹ Buhari sèpàdé pàjáwìrì nítorí ètò ààbò

Ipade pajawiri waye lonii, ojo isegun ni Aso Rock Abuja pelu awon eso alaabo Naijiria pata. Buhari ni inu oun ko dun si bi gbogbo nnkan se n lo yobo-yobo ni ilu. O ni gbogbo ohun to ba gba ni ki a fun-un. A ni lati sigun fun awon Boko Haram, ki a dawo awon ajinigbe duro.

Gabriel Olonisakin to je Oga awon soja lo n ba awon oniroyin soro yi nigba ti won pari ipade pelu Aare Buhari ni Abuja.

O si tun je ki o ye awon oniroyin pe gbogbo aso ko ni a n sa loorun ni ko ni le je ki oun so ju bee lo.

Ogagun John Enenche wa fajuro lori ero ayelujara to gbode. O ni ki awon ara ilu sora nipa awon ayederu iroyin to n jade si igboro. O fi oro Aare Buhari to so ni ojo Monde sapejuwe, o ni eni ti ko ba gbo oro Aare ni igba to n soo, le gbo ayederu nitori pe, oun gan-an ri eda ayederu oro Aare naa.

O ni bee naa si ni awon eniyan buruku n gbe ayederu opo nnkan kiri lati fori ara ilu gbara won tabi lati keyin awon ara ilu si ijoba. O ni gbogbo eleyii lo n fa ifaseyin fun ilu ti o si n si awon eso ilu lona.

Ogagun Enenche tun salaye ipa gidi ti ijoba n ko nipa ohun ija ogun fun awon. O ni ijoba gbiyanju gidi lori ohun ija ogun, o kan je pe ko si orileede to le ni gbogbo ohun ija ogun, koda titi de ile Amerika, won ko le fowo soya pe gbogbo ohun ija ogun ni awon ni.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…