Home ÀRÒJINLẸ̀ Ìwọ́de lórí Buhari
ÀRÒJINLẸ̀ - August 21, 2017

Ìwọ́de lórí Buhari

Iwode olojo bii ojo meje ti awon Deji Adeyanju ati Chalse Oputa ti gbogbo eniyan mo si Chaley Boy se da bi eni to ti n so eso rere. Won pe akole jijade won ni #OURMUMUDONDO#. Awon to se iwode yii ko po rara, won se ni “tian-tian ko ni eyin, bo se meji pere ko sa ti le wo eegun”. Ireti won ni ki awon omo Naijiria dara po mo won, ki won ye sunkun sinu sugbon won ko rero.

Gbogbo eniyan lo n fi won se yeye pe kin ni awon eniyan yii n wa ti won fi n se iwode. Awon olopaa tile ko lu won ni ojo keji iwode won. Gbogbo awon agbejoro lo dide pe ohun ti awon olopaa se ni Abuja lodi si ofin ile wa. Won ni gbogbo wa ni a ni eto labe ofin lati le rin ki a si yan, niwon igba ti a ko ba ti koja aaye wa.

Bi awon ara ilu ko se kun won lowo lati jade se iwode wa lara ipenija ti won ni. Awon kan tile gbeja ko won ni oja Wuse to wa l’Abuja. Awon elegbejegbe ati ologbajogba naa dide lati se iwode tiwon naa lasiko kan naa ni agbegbe kan naa.

Ose iwode kan naa ni Minisita eto iroyin ati asa ko awon iko oniroyin Aare sodi lo ilu London lati se abewo kiakia. Ose kan naa ni Bukola Saraki ati Yakubu Dogara se abewo, Ojogbon Yemi Osinbajo se tire, bee naa ni olori ijo Redeemed Enock Adeboye naa se abewo lose kan naa.

Iroyin si te mi lowo bayii pe Buhari ti wa lona lati maa pada bo wa si Naijiria. Ee rii pe iwode awon akoni bii mewaa yii so eso rere. Ohun ti ko ye emi ati opo eniyan ni pe, se Buhari ti setan ati maa bo wale ni abi iwode lo tete je ki ara ya. Iwode miran tile tun waye ni iwaju ile to n gbe ni ilu London. Bi a kuku se n yoo so naa ni a n yoo gbo.

Ti ara Buhari ba ti ya tele, kin ni o n se ni ilu Oba? Abi awon arije nidii madaru kan tun wa to n je nnkan buruku ti ko tii han saraye bi Buhari o se si nile?

Aisi nile ologbo ti so ile di ile ekute, gbogbo awon to se owo ilu maku-maku ni won ti fere jade ni atimole tan. Yoruba bo, won ni “eni ti a ba apa lowo re lo fapa ya”, orileede yi ti fere da owe naa ru. Awon ti a n ba owo lowo won ni ilu yii tun fere le maa gbe ijoba apapo lo ile ejo pe kin lo de ti e fi n toju bo eedegbeta milionu naira ti mo bo mole. Oro Naijiria to-to fun un!

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…