Ó wù mí kí gbogbo ọmọ mi jẹ́ obìnrin – Tunde Bakare
Oludari Agba fun ijo Latter Rain Assembly, Pastor Tunde Bakare, ti so pe nigba ti oun ati iyawo oun si n bimo lowo, ohun to wu oun ju ni ki gbogbo awon omo oun je obinrin.
Eleyii yato gedegede si ohun ti opo eniyan, paapaa awon omo Adulawo, maa n ro lokan.
Okunrin ni won maa n fe bi tori won gba pe awon okunrin ni arole.
Sugbon ni ti Bakare, obinrin lo wu u.
O se alaye idi oro naa ninu iforowanilenuwo kan to jade lojo Sunday.
O ni oun mo pe nigba ti obi ba dagba, awon omobinrin lo maa n toju re daadaa.
Sugbon sa o, iyawo Bakare ko ri bee. Oun n fe okunrin.
Ni igbeyin-gbeyin, Olorun pin in fun won ni. Ninu omo marun-un ti won bi, meji je obinrin nigba ti meta je okunrin.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…