Dídé Buhari máa dáwọ́ ìsiyè-méjì duro – Lai Mohammed
Minisita fun eto iroyin ati asa ni orileede yii, Alhaji Lai Mohammed lo n ba awon oniroyin soro ni papako Ofurufu ti ilu Abuja nigba to lo pade Aare Buhari ti o ti fi ilu sile lati ojo keji lelogorun. O ni dide Aare maa dawo isiye-meji awon eniyan kan duro dandan.
Minisita ni gbogbo igbiyanju awon egbe APC lati salaye pelu aworan ati fidio ni awon kan si gbagbo pe a dogbon sii, sugbon bayii, o ti han si gbogbo aye pe Buhari si le rin, o si le soro daadaa.
Gbogbo awon oloye ati awon gomina egbe oselu APC lo ti n ki Buhari ni orisiirisii ona, awon kan n pe lori foonu nigba ti awon kan lo pade re ni ilu Abuja. Oju ona to o gba de Aso rock naa kun fofo fun awon ero lati kii kaabo.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…