Home Orisirisi Oran de, Olatunde Akapo na omo Ibo loogun pa
Orisirisi - August 18, 2017

Oran de, Olatunde Akapo na omo Ibo loogun pa

Wahala nla kan ti be sile ni agbegbe Ibogun ni Ipinle Ogun nibi ti okunrin kan ti oruko re n je ti na omo Ibo kan ni oogun pa.

Iroyin fi ye ni pe gbonmi-sii, omi ko to o kanlo sele laarin Olatunde ati omo Igbo naa ti oruko re n je Augustine Ode. Won ni ibi ti won ti n tahun sira won, ti won fe wo idimu ni Olatunde ti sare wo yara re lo, to si mu oogun buruku naa jade, to si fin a Augustine.

O seese ko je ounde ajebiidan kan ni.

Ere ni awada ni, ibi ti Augustine subu si naa lo ku si.

Atejade kan lati owo ajo olopaa Ipinle Ogun, ti Oga Olopaa Abimbola Oyeyemi fi owo si, so pe won ti mu Olatunde si atimo bayii, ti won yoo si iwadii lori isele naa yoo sib ere ni kankan.

O seese ki isele ati iwadii naa mu iruju nla lowo. Idi ni pe opo eniyan yoo maa wo o bi ofin oyinbo ti a n lo yoo ti fie nu re mule pe oogun dudu lo pa Augustine.

Nje ofin gba pe oogun dudu le pa aniyan?

Bawo ni won se fe se amudaju pe ounde naa lo pa oloogbe – laise ibon tabi ada?

Oro naa tun mu iyanu lowo pe oogun Yoruba le mu eya miiran

Ki Olorun ba nib a esu wi.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…