Asari Dokubo ní òpònú ni Dieizani
Ajajagbara omo Niger Delta, Alhaji Asari Dokubo, ti soro ibinu si Minisita fun Oro Epo Robi tele, Iyaafin Diezani Allison-Madueke.
Isele to n sele lenu ojo meta yii, ninu eyi ti won ti n ka esun owo kikoje si i lese, ti won si n gba dukia re, lo fa a ti Asari fi n binu.
Kii se pe okunrin naa so pe ole ni Diezani. Ko si so pe o se ohun ti ko daa bo ba na owo Naijiria.
Dipo bee, o so ninu fidio kan pe iwa agabagebe ni ijo Buhari n hu nipa lile Deizani kiri, ti won si n finna mo o pe o ko owo je.
O ni awon agbaagba Hausa ati Fulani naa ti ko nnkan nla nla mo Naijiria lara, to si je pe eni kankan kop e won ni wobia wombiliki.
O ni nigba ti Diezani wa nipo, ti awon omo Naija Delta ba lo ba a pe ki o fun awon ni awon anfaani kan, boya nipa lanseesi lati maa fo epo, o maa n so pe won ko ni eto ati agbara lati se bee.
O wa dun Asari pe oro naa lo dele yii, ti won wa n ya Deizani perepere.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…