Home iroyin Àyájọ́ ọdún àwọn ọ̀dọ́ Lágbàáyé lárinrin
iroyin - August 16, 2017

Àyájọ́ ọdún àwọn ọ̀dọ́ Lágbàáyé lárinrin

Ọjọ abamẹta to kọja yii, tii ṣe ọjọ kejila oṣu ti a wa yi ni ayajọ ọdọ lagbaye. Ajọ UN (United Nations) lo ya ọjọ yi sọtọ ki wọn fi ṣayẹyẹ awọn ọdọ lagbaye. Akọle ayajọ tọdun yi ni ‘Youth Building Peace’ (Ọdọ to n fẹ isinmi). Ọpọlọpọ ajọ ni o ṣayẹyẹ ayajọ awọn ọdọ bii; Oluṣẹgun Ọbasanjọ Presidential Library (yara ikawe ti Ọbasanjọ kọ si Abẹokuta), ajọ S.M.I.L.E ati bẹẹ bẹẹ lọ. Ijọba ipinlẹ Eko naa ko kẹyin ninu ayẹyẹ naa.

Lati ṣayẹyẹ ayajọ ọdọ lagbaye tọdun yii, ijọba ipinlẹ Eko ya ọjọ marun-un silẹ lati ṣe. Wọn bẹrẹ pẹlu ki awọn ọdọ fi ẹbun ti wọn ni han, eyi to waye ni ọjọ kẹwaa ni Onikan. Kọmiṣọna fun ọdọ ni ipinlẹ Eko, arabinrin Uzamat Akinbile Yusuf jẹ ka mọ pe wọn gbe eyi kalẹ lati ran awọn ọdọ to ni ẹbun amọ ti ko si gbagede to ma gbe wọn jade gẹgẹ bi olorin, onijo tabi akewi. O fi akoko naa rọ awọn ọdọ ki wọn ma ya mọdaru gẹgẹ bi akọle ayajọ ọdun yi ṣe sọ. O sọ pe ijọba ipinlẹ Eko n ṣeto idanilẹkoọ fun awọn to ma nifẹ si gbigbe ẹbun wọn larogẹ. O ni awọn ma jẹ ki gbogbo ọdọ mọ nigba ti wọn ba bẹrẹ.

Fun ọjọ keji, wọn ṣe adura awọn musulumi ni mọṣalaṣi to wa ni Alausa. Ni ọjọ ayajọ gangan, wọn ṣe iwọde lati Papa-isere Teslim Balogun  lọ si olu ile-iṣẹ ijọba ni Alausa. Wọn ṣe ifihan ati itakurọsọ ni ọjọ kẹta ni Alausa. Ibẹ ni gomina ipinlẹ Eko ti gba awọn ọdọ niyanju nipa iwa ọmọluabi.

Eto to ma kadii ayẹyẹ naa ni adura ni ile ijọsin ti ‘Chapel of Christ Our Light’ ni Alausa, Ikẹja ni ogunjọ oṣu yi.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…