Home iroyin Wàhálà ojú Lanrewaju Adepoju: Mílíọ̀nù kan péré ló tíì wolé nínú méje
iroyin - August 15, 2017

Wàhálà ojú Lanrewaju Adepoju: Mílíọ̀nù kan péré ló tíì wolé nínú méje

Àgbà akéwì ní, “Ẹ gbá mì, ẹ má jẹ́ k’ójú mi ó fọ́ tán’

FEMI AKINSOLA

Bi aayan se n lo lori ati ri owo lati se ise abe fun ogbontarigi akewi, Oloye Olanrewaju Adepoju, IROYIN OWURO ti gbo pe omi si po lamu lori iye owo ti awon dokita n fe o.

A gbo pe ninu milionu meje ti won n wa, owo bii milionu kan pere ni won tii ri.

Se Yooba bo won ni oju ni imole ara, ati pe oju la fii pete ero. Hun! O je nnkan ibanuje gbaa pe bi Olorun se bu kun wa lorile yii to, opo nnkan ni o nuwa, latari ailakasi, ati ailafojusun to gunmo fojo iwaju. Bi bee ko, se o ye ki wahala to bayii lorun Oloye Olanrewaju Adepoju, eni ti o fi ijinji aye e re sin orile yii, titi dasiko yii lai ro kiko oro jo; sugbon ti o wa di asiko to ye ki ilu gbaruku tii, ti awujo wa n yori boro boro.Bi ko ba ri be e, se ko jo be e. Agba pede-pede, oba ewi yii ni ipenija oju lati nnkan bii odun die seyin, ti o si ti gbiyanju ,debii pe apa ti kun un, latari pe owo apekanuko ja baba yii ni tanmo o.

Ninu eto o ori redio kan ti won fa baba naa ni teete wa ni o ti tu pere-pere pe won ko bi oun ni afoju o, sadede loju naa bere, ti oun si ro pe nnkan kekere ni,sugbon awon kan ti won so pe awon n sise abe iwosan oju ni won gbiyanju lori oju naa,sugbon, ti ayewo pada fidi re mule pe okun teere kan ti o so oju po fun irorun gaaara ( retina) ti ja. Ni kukuru ede, baba naa so pe awon akosemose ti gba oun nimoran pe oke okun ni atunse to fokanbale ti le wa si oju naa,bi be e ko,bi yoo se wa niyen .Anjaanu akewi naa so pe,gbogbo ise opolo ti oun ni lokan, ni idaamu oju yii ti begi dina won.

Ogbontarigi akewi naa ni apa kun oun ni o, tori pe owo ti o to milionu meje naira (N7m ) ni awon dokita nilo, lati sise abe oju naa ni orileede India. Baba naa ni inu oun yoo dun pupo bi oun ba ri alaaanu iranwo owo ki oro naa to yiwo .Se awon agba bo won ni ko si n to bagba ninu je bi ifa ti ko lebo ‘ti ko letutu. Idunu saa ni ounje agba.

Iroyin Owuro gba pe o ye ki omo Yooba atata o le kopa ti o joju lori oro baba yii. O fe e ma si ojulowo omo Yooba ti ko ti bu mu ninu omi ogbon ohun imo Oba ewi yii.  Yoo buru jai ki a ma lakasi ara a wa lasiko isoro,sugbon ki a maa wa pokiki irufe eni be e ati ise owo o re leyin ti o ba rare ti iku fi ran an ni irinajo aloode.

Yoruba ronu o. Teni n teni takisa n taatan. N je tolori telemu, otookulu, oba ati ijoye,  gbogbo eleyinju aanu pata, omo Yooba atata yii, Lanrewaju Akanmu Adepoju, dowo yin. Eleeru ko gbodo sungi o. Ijafara lewu, eeyan ti ko si tii ku, ko i mo iru iku ti yoo pa a. E pe olootu fun iranwo lori oro baba yii.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…