Home ÀRÒJINLẸ̀ Nàìjíríà ń lọ iwájú àbí ẹ̀yìn?
ÀRÒJINLẸ̀ - August 15, 2017

Nàìjíríà ń lọ iwájú àbí ẹ̀yìn?

Omo Naijiria, a ma ku ojo meta, a ku oro ilu ti ori da wa si. Yoruba bo “ won ni ibi ori ba da ni si laa gbe”. Bi asa Oloogbe Kola Olawuyi, o maa n sabaa so pe “ile aye ko saa ni le titi, ki a lo inu omi loo maa gbe, nigba to je pe awon eja ni Eledua se ibe fun”.

Ewo ni a ro ti ko too ro, se ki a bere pelu awon asofin ti a ni ki won wa wo “gobi ti won ni kin niyi gobi-gobi” a ni ki won ba wa tun ilu to, ki adinku le ba owo rogun-rogun to n wole si apo won, ki ounje eemeta le daju lojumo fun ara ilu, ti won ko jale pe iru atunto bee ko see se, dipo bee, won tun n fi agbara kun agbara won ni.

Aisi nile Aare Buhari n ko? Ohun naa n da ere ori itage tire sile. Awon kan bere iwode ni ojo Monde, won si see di ojo jimo gbako bi o tile je pe won ko po rara. Ohun ti won n beere fun ni ki Buhari wale lati ilu Oba tabi ki o kowe fi ipo re sile. Ojo keta ti won bere  ni awon miran naa bere tiwon ni ori papa kan naa ni ilu Abuja. Awon ni ti Buhari ni awon n se ni gbogbo igba. Won ni Buhari ko tii se si ofin kankan nitori pe o gbe agbara sile fun igbakeji re ko to lo ilu London. Awon yii tile fe ba awon to ni ki Buhari kowe fi ipo sile ja ni ojo Jimo, opelope awon Olopaa to ko si won laarin.

Ni agbegbe Eko si Abeokuta, ajaale lo n se ijoba nibe. Won ri ajaale kan ni ojo Isegun ni adugbo kan ti won n pe ni Obadeyi Ajala, ki  a to de Ijaye ni opopona Eko si Abeokuta. Awon ara ilu fi ibinu dana sun die ninu won, awon Olopaa ko die lo mo awon to n binu lowo. Won ba opolopo nnkan awotele obinrin ni agbegbe ile kan ni ibe.

Ojo keta tii se ojo Alamiisi ni won tun ri omiran ni adugbo kan ti won n pe ni ile Zik, opopona kan naa ni o wa pelu ti ojo Tuside. Won ba opo nnkan ilo obinrin naa nibe bi o tile je pe awon olopaa ni were ni eni ti won fe dana sun ni adugbo naa.

Ojo alamiisi yii kan naa ni awon ero tun pe le Baba kan ati iya kan lori ni adugbo Ketu, ni Eko kan naa. Eleyii sun mo adugbo CMD Road. Ohun naa koko bere bi ere ori itage, won ni okunrin kan lo tuto koja lori omo kekere kan, ti mama kan wa gbee kanri lati gbeja omo naa, ase mama naa lo fe dogbon gbe omo yii lo. Ki a to wi ki a to fo, awon ara Eko ti ja obinrin naa si ihoho ki awon Olopaa to gbe obinrin naa lo si ago won ni Ketu.

Ojo Jimo ni omiran tun sele ni ilu Abeokuta, ti won ka orisiirisii eya ara mo ojubo awon kan ni ilu naa. Awon olopaa si ti fi owo sinkun ofin mu die ninu awon onise ibi naa.

Ose to koja ni awon eniyan kan n fi fidio Alhaji kan han kiri ni ibi to ti mu awon olopaa kiri ojubo ti won ti n se ise ibi won, ti awon olopaa si n fi idi ibon ati ese fo opo awon ilekun ojubo naa.

A ko tii fi gbogbo ara bo lowo ogun ti BADOO to n gbeje. Nibo la wa n lo ni ilu yii? Kin ni a fe da gan-an? Ti a ba tile ni gbogbo owo ati oro ile aye yii tan, se a fe ju saye lo ni? Boya ni awon eniyan mo pe opo emi ti ko ni dola lo n dosu mejila.

Nibi ti aye laju de, ti awon Oyinbo n se iwadii lojoojumo. Won n gbe ise opolo yo lori imo komputa ati imo ero miran ni gbogbo igba. Ona oloda to yo kuuruku lasan ti ko nilo nnkankan lati oke okun, a ko rii se. Ojoojumo ni a n padanu emi nitori ona ti ko dara, a ko ri ina se, onikaluku lo gbe kanga igbalode fun anfaani ebi re. Ko si ise nilu, ko sowo, a ko si rii ro rara. O ma se o. E o ri ibi ti awa laju de. Ibi ti awa ba iwadii tiwa de ni a ri yii o. Eje ara wa lati fi sowo tabi gba agbara ni aye olaju yii. O bo lowo omo to n jeeru. E maa wo abala www.iroyinowuro.com.ng ni gbogbo igba. Fidio kan wa ti enikan fi ranse si mi, ona ara ti o wa lati orileede China lo si Pakistan. E maa ri iyato ninu arojinle wa ati awon to ku lagbaaye.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…