Home iroyin Aláàánú Mẹ̀kúnnù ni Ọnarébù Sugar jẹ́ – Arábìnrin Soetan
iroyin - August 15, 2017

Aláàánú Mẹ̀kúnnù ni Ọnarébù Sugar jẹ́ – Arábìnrin Soetan

Yoruba bọ won ni yinni yinni kẹni o ṣe omiran. Bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri ni opin ọsẹ to kọja yii nigba ti oniṣowo pataki kan ni ipinlẹ Ọyọ, iyẹn arabinrin Soetan Temilade Folukẹ,  sọ okodoro ọrọ pẹlu akọroyin wa OLUSEYI ONI ni opin ọsẹ to kọja yii pe, lara awọn oloṣelu to jẹ ọlọpọlọ pipe, ti o si fẹran mẹkunnu denu ni ọnọrebu Ọlatoye Temitọpe Sugar jẹ laaarin awọn oloṣelu ẹlẹgbẹ rẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni akoko yii.

Iyaafin Soetan sọ ọrọ yii di mimọ ni opin ọsẹ to kọja yii nigba ti o n fi ọrọ jomitoro ọrọ pẹlu akọroyin wa ni ile iṣẹ rẹ eyi to wa ni Ilu Ibadan lori  tani yoo di Gomina ipinlẹ Ọyọ ni ọdun 2019,  ni kete ti Gomina ipinle naa iyen Sẹnatọ Abiọla Ajimọbi ba pari saa rẹ eyi to ti dawọle ni ipinlẹ Ọyọ lati ọdun mẹfa sẹyin bayi.

Iyaafin Soetan jẹ ko di mimọ pe Gomina ipinle Ọyọ Sẹnatọ Abiọla Ajimọbi ṣe gudu gudu meje lati mu igbe aye dẹrun fun awọn eeyan ni ipinlẹ Ọyọ lati ọdun mẹfa ti o ti wa ni ori aga apaṣẹ ni ipinlẹ Ọyọ. O ni nitootọ, ọpọlọpọ awọn ọlọpọlọ pipe oloṣelu ni o wa ni ipinlẹ Ọyọ paapa ninu ẹgbẹ A.P.C ṣugbọn ẹni ti oun ri gẹgẹ bi ẹni to le ṣe iṣẹ rere fun awọn mẹkunnu gẹgẹ bii Gomina ipinlẹ Ọyọ ni ọdun 2019 to si lee gunle iwa rere eyi ti Gomina Ajimọbi dawọle ni ipinlẹ Ọyọ ni ọnọrebu Ọlatoye Temitope Sugar.

Arábìnrin Soetan, to je ọkan lara awọn oloṣelu ti o ṣiṣẹ fun Gomina ipinlẹ Imo, iyẹn Gomina Rochas Okorocha ti ọpọ eniyan mọ si Owelle, ni Ilu Abuja ni ọdun 2002 ni akoko ti o fẹ lọ fun ipo Aare orilẹ-ede yii, amọ ti o ti fi Ilu Ibadan ṣe ibujoko rẹ ni agbegbe Ijọba Ibilẹ Ido, sọ pe, Ohun iyalẹnu ni o jẹ fun ọpọ awọn ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ nigba ti wọn gbọ pe ọpọ awọn oloṣelu ni o nifẹ lati di Gomina ni ọdun 2019. O ni ọpọ ninu awọn eniyan wọnyi ni ko ka ju ẹ, bẹẹ si ni, pupọ ninu wọn ni ko ni Ife mẹkunnu lọkan, gẹgẹ bii ọkunrin ọmọ bibi ijọba Ibilẹ Lagelu ni Ilu Ibadan, ti ọpọ eniyan kakakiri ipinlẹ Ọyọ mọ si, Alaanu Mekunnu, kakakiri gbogbo Ijọba Ibilẹ ti o wa ni Ipinle Ọyọ.

Arabinrin Soetan jẹ ko di mimọ pe, gbogbo iṣẹ rere eyi ti ọnọrebu Ọlatoye Temitọpe Sugar gunle ni ko ṣokunkun si gbogbo ọmọ bibi ipinlẹ Ọyọ. O ni iwa aanu eyi ti ọkunrin naa n ṣe ni o keefin Iru eniyan Alaanu ti o jẹ laarin awọn oloṣelu ẹlẹgbẹ rẹ lawujọ. O ni ọpọlọpọ awọn oloṣelu ẹgbẹ rẹ ni ko lee ṣe iṣẹ rere eyi ti Ọlatoye n ṣe ni akoko yii.

O wa yannana ọrọ rẹ pe, ninu gbogbo awọn oloṣelu ti awọn eniyan darukọ pe wọn nifẹ lati gbe igba idibo si ipo Gomina ni Odun 2019 ninu Egbe, A.P.C, PDP, ACCORD ati S.D.P tani o se e ohun ti Ọlatoye n ṣe lati ṣe iranlọwọ fun awọn mẹkunnu, ati lati ṣe iranwọ fun gbogbo Ijọba Ibilẹ to wa ni ipinlẹ Ọyọ. O wa sọ di mimọ pe ọnọrebu Ọlatoye ko duro ni ijọba ibilẹ rẹ nikan lati ṣe iṣẹ rẹ, o ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Ọyọ ni won ti n jẹ anfaani ọnọrebu naa.

Arabinrin naa tẹ siwaju ninu ọrọ rọ pe, ẹni ti yoo jẹ Gomina ipinlẹ kan gbọdọ ni imọ nipa gbogbo ohun to n lọ ni gbogbo ijọba ibilẹ to wa ni abẹ rẹ. Bẹẹ si ni irufẹ eniyan bẹ gbọdọ lee tọka si ohun pataki ti o ti ṣe ṣiwaju fun awọn ara ilu naa. O ni bẹẹ gẹlẹ ni ọrọ ri ni ipinlẹ Ọyọ bayi, nitori eni ti o fẹ ṣe Gomina gbọdọ ti ni imọ nipa iṣoro eyi ti ijọba ibilẹ kan n koju ki o to de ori aga. Paapaa iha to kọ si itọju awọn mẹkunnu latẹyinwa, ka maa purọ, mẹkunnu pọ ju ọlọla lọ kakakiri ipinle ti o wa ni orile ede wa lọwọ lọwọ bayi. O wa sọ di mimọ ninu ọrọ rẹ pe lara awọn oloṣelu ti awọn eniyan darukọ pe awọn nifẹ lati di Gomina ni ọdun 2019 ni ko nife Mmẹkunnu lọkan rara. Ifẹkufẹ ara wọn lo fẹ jẹ ki wọn du ipo ni ọdun 2019. O wa yannana ọrọ rẹ pe, pupọ lara awọn eniyan wonyi ni ko gbe ni ipinle Ọyọ, o ni ọpọ ninu wọn n gbe ni ilu Oyinbo ti ọpọ si n gbe ni Ilu Eko. Kinni ohun ti irufẹ eniyan bẹ le mo nipa iṣoro ti awọn eniyan rẹ n koju ni agbegbe rẹ ni ibeere ti obinrin naa beere. O wa sọ di mimọ pe, ọnọrebu Olatoye Temitope n ṣe iṣẹ oojo rẹ gẹgẹ bi amofin ni ile igbimọ aṣofin kekere ni ilu Abuja, O ni ọṣọọsẹ ni ọnọrebu naa maa n wa si ilu Ibadan lati wa fun awọn ti o ran niṣẹ labọ iṣẹ ti wọn ran lọ ṣe ni ilu Abuja.

O wa tẹnu mọ ninu ọrọ rẹ pe, gbogbo ijọba ibilẹ ni ipinlẹ Ọyọ ni o mọ daju pe ọnọrebu naa maa n wa si ilu Ibadan ni Osọọsẹ. O ni eyi ko ṣokunkun si gbogbo ara ilu ni igbooro Ilu Ibadan, O ni idi niyi ti wọn fi sọ ile igbafẹ rẹ di Mecca ni gbogbo ọjọ Jimọ, nitori ẹni ti o ba ba ẹkun de ibẹ o di dandan  ki irufẹ ẹni bẹ rẹrin jade ni. Iru oloṣelu wo ni o le ṣe eyi ni ipinlẹ Ọyọ ni ibeere ti obinrin naa n beere ni ọjọ naa.

O ni ẹni ti ko ni itan iṣẹ rere kankan tẹlẹ lati tọka si, ti o kan wa ni pajawiri lati wa gbegba idibo, o ni iru eniyan bẹ ko le ṣe aṣeyọri kankan, nitori owo ti wọn fẹ ko je ni iru eniyan bẹ wa wa. Bakan naa ni o tun tẹnu mọ ninu ọrọ rẹ pe ki awon eniyan ma fura si awọn oloṣelu ti wọn ba n lo oruko rere awon oloṣelu atijọ ti wọn ti ṣe iṣẹ rere silẹ lati maa fi polongo idibo fun ara won. O ni iru awọn eniyan bayii ko yẹ nipo. E jẹ ki awọn naa sọ ohun ti wọn ti ṣe fun araye lasiko ipolongo idibo ara wọn, ki awọn eniyan lee mo boya eeyan rere ni wọn lawujọ, ni ọrọ imọran ti o fi pari ọrọ rẹ.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…