Home ERÉ ÌDÁRAYÁ Kò yẹ kí Ronaldo gba “Red Card” – Zidane
ERÉ ÌDÁRAYÁ - August 14, 2017

Kò yẹ kí Ronaldo gba “Red Card” – Zidane

Akoni-moogba egbe agbaboolu Real Madrid, Zidane ni ko ye ki Refiri fun Ronaldo ni kaadi pupa to fun un rara. O ni kin la gbe, kin le ju ni itumo kaadi naa. O ni loooto ni ohun ti  Ronaldo n dogbon beere fun o ki n se penariti, amo ko tona ki o wa je iya ona meji. O fo lati dogbon beere fun penariti, nigba ti ko bo sii, ko leto iru iya to po to bee.

Bee ni awon kan ni o ye ki Ronaldo gba nnkan miran to ju kaadi pupa lo to ba wa. Won ni eni to ba wo boolu naa daadaa lo maa le salaye. Ibi idije naa ni Real madrid ti na awon iko Barca ni ayo meta si eyokan (3-1).

Won ni Ronaldo yii kan naa ni o gba boolu wole alatako to bo ewu re to soo si aarin ero, oun kan naa ni o tun lo fo lati dogbon gba penariti, oun naa lo tun fowo ti refiri De Burgos Bengoetxea laya ko to jade kuro lori papa isere naa.

Zidane ni gbogbo ohun to ba gba ni awon maa fun un ti Ronaldo fi maa le gba boolu ni ojo weside.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…