Kò síjà láàrin èmi àti Tinubu – Muiz Banire
Amofin agba ni orileede yii (SAN) Muiz Banire lo n salaye fun awon oniroyin pe ko si aawo kankan laarin oun ati Asiwaju Bola Tinubu. O ni ko si ariyanjiyan kankan lati odo oun pe Tinubu ni Asiwaju agba fun egbe APC l’Eko ati ni Naijiria.
Banire ni awon ti ko mo ofin ti won ko si mo ohun to kan ni won n gbee poori enu pe awon maa yo oun kuro ninu egbe oselu APC, won ko tile mo nnkankan nipa ofin to de egbe, won ko mo pe ipinle ko lase lati yo iru oun kuro ninu egbe APC.
O ni ilu Abuja ni won ti le yo oun ti won ba ka iwa ibaje mo oun lowo. O ni eni to ba n tele ohun to fa faa- ki- a-jaa laarin oun ati awon kan ninu egbe naa, won maa rii wi pe, ofin ni oun n tele. Oun nife si ki awon se egbe naa bi o se ye ki awon see ki o le ba ri bi o ti ye ko ri.
Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole
Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…