Home iroyin Èmi nínú ẹgbẹ́ PDP, Èèwọ̀ – Segun Oni
iroyin - August 14, 2017

Èmi nínú ẹgbẹ́ PDP, Èèwọ̀ – Segun Oni

Gomina tele ni ipinle Ekiti, Oloye Segun Oni ni o ja iro awon eniyan to n gbee kiri pe o n se ipade bonkele pelu Alagba Markarfi to je Alaga egbe oselu PDP ni Ifaki-Ekiti tii se ile re. O tun ni won paro mo oun pe oun ati Gomina lowo-lowo ni ipinle Ekiti, Alagba Ayodele Fayose naa ti n se ipade bonkele miran ni ile-itura kan ni Eko.

Segun oni ni Olorun ma se je ki oun ri apadasi aburu, kin ni oun fe maa wa kiri ti oun fi maa lo si egbe PDP. O ni ko si ohun to jo iru iro banta-banta ti awon ota oun n gbe kiri, paapaa julo lori ero ayelujara. O ni ohun ti oro awon aleheso naa ko fi dun oun ni pe gbogbo aheso ti won ro pe awon le fi ja irawo oun kan tun n mu ki oun gbajumo sii ni laarin ilu.

O ni ko tile si ohun to tii gbe oun ati Markafi po ni ojukoju ni igba kankan, o ni riri ni ojukoju ti Fayose gan an waye ni igba ti isinku Ologbe Adebayo. O ni lati igba naa ko tun si ohun to gbe awon po ni ibi kankan mo.

Gomina tele naa ni loooto ni oun fe dije du ipo gomina ipinle Ekiti leekan sii amo kii se pe gbogbo ohun to ba gba ni awon maa fun un.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…