Home iroyin Àwọn ìpátá yarí mọ àwọn asòfin Edo lọ́wọ́
iroyin - August 14, 2017

Àwọn ìpátá yarí mọ àwọn asòfin Edo lọ́wọ́

Onorebu Justin Okonoboh ni ile-igbimo asofin ipinle Edo ti fi ibo da duro ni oni ojo kerinla, osu kejo odun yii. Won ni ko tele ofin bi o ti to ati bi o ti ye, ni eyi to lodi si idasile ile-igbimo asofin naa. Won ni o tun maa n gbese fun agbasese ni ona aito.

Loju ese ni won fi Kabiru Adjoto to n soju AkokoEdo ropo olori naa gege bi ofin se laa sile. Kia naa ni awon omo ipanle ti dide ti won si gba ile igbimo asofin Edo lo lati lo fehonu han pe awon ko fara mo bi won se yo Onorebu Okonoboh gege bi olori ile igbimo naa.

Awon omo ipanle yii ni won ko pe iye to ye ki won pe lati yo Sibika naa ati wi pe ti won ba tile fe yo Onorebu naa, o ye ki won fi elomiran ropo re lati woodu re to ti jade, ko ye ko je lati Akoko Edo rara.

 

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Ó yẹ kí INEC tọrọ àforíjì lọ́wọ́ ọmọ Nàìjíríà – Oshiomole

Asiko ti olori ajo INEC n ba awon oniroyin ati gbogbo elegbejegbe ati ologbajogba ni ilu A…